Ile ti Ayọmide ti lọọ ṣiṣẹ lo ti ji jẹnẹretọ, ọwọ Amọtẹkun ti tẹ oun ati Hausa to ta a fun l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọdekunrin kan, Ayọmide Akande, ti n ran awọn oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ nipinlẹ Ọṣun lọwọ ninu iwadii wọn lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.

Lati ilu Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun, la gbọ pe Ayọmide ti wa ṣiṣẹ birikila l’Oṣogbo. Lanlọọdu ile kan to wa lẹyin ileetura Galaxy lo gbe iṣẹ kan fun un, wọn si jọ ṣadehun ẹgbẹrun mẹẹẹdogun gẹgẹ bii owo iṣẹ.

Bi lanlọọdu ṣe kuro ninu ile ni ọmọkunrin yii ri jẹnẹretọ nla kan to jẹ ti akẹkọọ-binrin to yale gbe ninu ile naa, ko si jẹ fi falẹ rara to fi wọ jẹnẹretọ naa sita, to si gbe e lọ.

Hausa kan lagbegbe Old-Garage, lo ta jẹnẹretọ ti wọn ni owo rẹ to ẹgbẹrun lọna igba naira ọhun fun ni ẹgbẹrun marun-un naira pere.

Nigba ti oni nnkan pada de, to kegbajare fun awọn araadugbo pe oun ko ri jẹnẹretọ oun mọ ni awọn ti wọn ri Ayọmide nigba to n gbe e lọ sọ fun akẹkọọ-binrin naa pe birikila ti lanlọọdu mu wale lo gbe e.

Bayii ni wọn wa Ayọmide lọ sibi to n gbe, nigba ti ko tete jẹwọ ni wọn ke si awọn Amọtẹkun, ko too di pe awọn eeyan yoo ṣedajọ fun un lọwọ ara wọn.

Ọdọ awọn Amọtẹkun lo ti jẹwọ, o si mu wọn lọ sọdọ Hausa to ta a fun. Hausa sọ pe oun maa n ra iru awọn nnkan bẹẹ, ti oun yoo si tun awọn ẹya-ara rẹ ta ni toun ni.

Bayii lawọn Amọtẹkun fa awọn mejeeji le awọn DSS lọwọ fun iwadii to peye lori iwa ti wọn hu.

Leave a Reply