Faith Adebọla
Ileeṣẹ Aarẹ ilẹ wa ti ṣe sadankata sawọn oṣiṣẹ ẹka ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa atawọn agbofinro ti wọn lọwọ ninu bi wọn ṣe mu adari ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu, ati bi wọn ṣe lọọ ṣakọlu sile Oloye Sunday Adeyẹmọ (Sunday Igboho).
Atẹjade kan ti Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Mallam Garba Shehu, fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, l’Abuja, sọ pe awọn ẹṣọ alaabo agbaye lo kun ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lọwọ tawọn fi ri Nnamdi Kanu mu, kawọn too gbe e pada wale lati waa jẹjọ to wa lọrun ẹ.
Ni ti Sunday Igboho, o ṣapejuwe ọkunrin naa bii adunkooko-mọ-ni ẹda, to dinbọn pe oun n daabo bo awọn eeyan oun nilẹ Yoruba ni, ṣugbọn to jẹ omi alaafia ilu lo n daru kaakiri, awọn ọrọ to si n jade lẹnu jẹ ọrọ ikorira ẹya ati ọrọto le dogun silẹ.
O ni bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ Aarẹ mọ pe awọn eeyan lẹtọọ labẹ ofin ẹtọ ọmọniyan, sibẹ, awọn o le laju silẹ ki talubọ ko wọ ọ, kawọn maa woran titi tẹnikan yoo fi ko nnkan ija ogun jọ, ti yoo si ba iṣọkan Naijiria jẹ.
Apakan atẹjade naa ka pe: “Lọsẹ to kọja yii, a ri i bawọn ẹka ileeṣẹ agbofinro ilẹ wa ṣe fọwọsọwọpọ ṣiṣẹ, ti wọn si ṣaṣeyọri lati mu awọn eeyan kan ti wọn n fara ni araalu ẹlẹgbẹ wọn.
Lara iṣẹ takun-takun ti wọn ṣe lọjọ ki-in-ni, oṣu keje, Tọsidee, ni bawọn SSS (State Security Service) ṣe lọọ gbọn ile adihamọra ogun adunkooko-mọ-ni to n pariwo ipinya, to n dana ijangbọn kaakiri agbegbe kan.
Aṣẹ ti Aarẹ pa pe ki wọn yinbọn pa ẹnikẹni ti wọn ba ba ibọn AK-47 lọwọ ẹ ṣi wa lẹnu iṣẹ, ko si ruju rara. Tori naa, lai ka iru ẹni ti wọn jẹ ati apa ibi ti wọn ti wa si, ijọba maa ba wọn lo bii janduku ọdaran ni, wọn si maa foju wina ofin.
A gboṣuba fun aṣeyọri tawọn agbofinro wa ṣe wọnyi, wọn ti fihan pe awọn to gbangba a sun lọyẹ, awọn peregede lẹnu iṣẹ wọn, wọn si fẹnu mẹnu fete mọ ete titi ti wọn fi ṣaṣeyọri ni.
A rọ wọn lati maa ba iṣẹ wọn niṣo pẹlu ijafafa bẹẹ, ki wọn si ṣe bakan naa fawọn ti wọn sọ jiji ọmọleewe atawọn ara abule gbe di iṣẹ lapa Ariwa orileede wa.
Orileede yii mọyi iṣẹ atata tawọn agbofinro ṣe o.”
Bẹẹ ni Garba Shehu pari ọrọ rẹ, lorukọ ileeṣẹ Aarẹ.