Ileeṣẹ mi ti wọn jo, awọn ọta mi nidii oṣelu ni o – Bola Tinubu

Aderounmu Kazeem

“Ka ni mo fẹẹ lo agbara ni, gbogbo awọn janduku to kọlu awọn ileeṣẹ mi ni wọn iba ma fara rere lọ, ṣugbọn mi o ṣe bẹé nitori mi o fẹ ki wọn paayan kankan si mi lọrun rara.”

Eyi lohun ti Bọla Ahmed Tinubu, sọ ninu atẹjade kan to fi sita lati fi ṣe alaye wi pe oun ko lọwọ ninu bi awọn ṣoja ti ṣe kọlu awọn ọdọ to n ṣewọde lagbegbe  Lẹkki.

Tinubu sọ pe loootọ ni ileeṣẹ tẹlifiṣan TVC ati ileeṣẹ to n tẹ iwe iroyin The Nation jẹ dukia oun, ati pe ki wọn too kọlu wọn gan an ni ohun ti gbọ alami nipa ẹ, ṣugbọn ti oun ko ko ṣoja tabi ẹṣọ agbofinro kankan lọ sibẹ nitori oun mọ daadaa wi pe oku yoo sun, bẹẹ ni ko wu oun lati ni oku ẹnikẹni lọrun.

Aṣiwaju fi kun un wi pe niwọn igba ti oun ko ko ṣoja tabi ọlọpaa kankan lọọ ṣọ awọn dukia oun, ti gbogbo aye paapaa mọ pe toun lawọn ileeṣẹ ọhun n ṣe, ki lo waa maa mu oun dari awọn ṣọja lọ si too-geeti Lẹkki, nibi ti oun ko ni kọbọ si, tabi ni ipin idokoowo kankan nibẹ.

Ọkunrin oloṣelu yii ti waa sọ pe iṣẹ ọwọ awọn eeyan kan ti wọn koriira oun ni o, bẹẹ loun ko ni i tori dukia tabi ọrọ kankan ṣe ohun ti yoo sọ ẹmi eeyan nu.

Jagaban, bawọn eeyan tun ṣe maa n pe e,  sọ pe ohun to dun mọ oun ninu ju ni bi awọn oṣiṣẹ TVC ati The Nation ṣe bọ lọwọ ikọlu ọhun, ti ko si ẹmi oṣiṣẹ kankan to ba a lọ.

“Loootọ ni dukia ṣofo, ṣugbọn ọpẹ nla ni wi pe ẹmi oṣiṣẹ mi kankan ko ba a lọ. Emi o ni kọbọ ninu ileeṣẹ to n gba owo lọwọ awọn araalu ni too-geeti Lẹkki, bẹẹ lọrọ ileeṣẹ naa ko kan mi rara, ki i ṣe emi lo ran ṣoja niṣẹ o.” Aṣiwaju Bọla Tinubu lo sọ ọ.

 

One thought on “Ileeṣẹ mi ti wọn jo, awọn ọta mi nidii oṣelu ni o – Bola Tinubu

Leave a Reply