Ileeṣẹ ọlọpaa n wa agbofinro to n fa shisha ninu fidio kan 

Oluyinka Soyemi

Olu-ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ yii to wa niluu Abuja ti bẹrẹ iwadii lori fidio kan to n lọ kaakiri agbaye bayii, ninu eyi ti ọlọpaa kan ti n fa shisha, eyi to jẹ eefin ti wọn ṣe sinu akoto.

Ninu fidio ọhun ni ọkunrin to wọ aṣọ ọlọpaa naa ti n gbadun ara ẹ pẹlu siga aramanda yii ni kọrọ ile kan.

Ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa nilẹ yii, Frank Mba, fi sita, o ni iwadii ijinlẹ yoo waye lati mọ boya ojulowo ọlọpaa lẹni naa, tabi ayederu ẹda kan, tabi onitiata to n ṣe fiimu lọwọ.

O ni bo tilẹ jẹ pe aṣọ ọlọpaa lọkunrin naa wọ, eyi ko fi bi ileeṣẹ naa ṣe ri han nitori awọn eeyan gidi lawọn n gba siṣẹ.

O waa rọ araalu to ba mọ ọna ti ọkunrin yii fi le di riri lati kan si ileeṣẹ naa lori pressforabuja@police.gov.ng tabi awọn ẹka intanẹẹti wọn.

Fidio ọlọpaa to n fa shisha ọhun ree:

Leave a Reply