Ileeṣẹ ọlọpaa ti doola ẹmi akẹkọọ Fasiti KWASU ti wọn ji gbe ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, nileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, fi iroyin ayọ lede pe awọn ti doola ẹmi Isiaq Khọdijat, akẹkọọ Fasiti KWASU, tawọn ajinigbe ji gbe kuro ni akata awọn ajinigbe ọhun layọ ati alaafia lai fara pa, ti ọwọ siti ba awọn ajinigbe naa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fi lede ni ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, lo ti fi idi ọrọ naa mulẹ pe awọn ti doola ẹmi Khọdijat layọ ati alaafia, kọda, ọwọ ti ba awọn ajinigbe naa, ti wọn yoo si foju wina ofin ijọba.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ to kọja lawọn ajinigbe ọhun ji Khọdijat, akẹkọọ KWASU, to wa ni ipele kẹta (300 level), ni ẹka Mass Communication gbe ni Opopona Okoru, niluu Malete, ti awọn ajinigbe naa si n beere fun miliọnu lọna aadọta naira, owo itusilẹ. Ṣugbọn ni bayii, awọn ọlọpaa ni awọn ti doola ẹmi rẹ lai san owo itusilẹ kankan.

Leave a Reply