Ileeṣẹ ọlọpaa ti le Sajẹnti Adamu to yinbọn pa Ọmọọba l’Oṣogbo lẹnu iṣẹ

Ileeṣẹ ọlọpaa ti le Sajẹnti Adamu to yinbọn pa Ọmọọba pa Ọmọọba l@fun igbẹjọ ati ijiya to tọ.

A oo ranti pe lọjọ kẹtadinlogun, oṣu keje, ọdun yii, niṣẹlẹ buburu naa ṣẹlẹ ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ loju-ọna Ọ̀bà, lagbegbe Islahudeen to jade si Ring Road, niluu Oṣogbo.

Lasiko ti awọn ọlọpaa kogberegbe naa n kọja ninu sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ lagbegbe ọhun ni ọkan lara wọn yinbọn soke, to si ba Saheed loju.

Latigba naa lo ti wa nileewosan UNIOSUN pẹlu ẹnjinni ti wọn fi n mi lẹnu rẹ, ṣugbọn to jade laye lọgbọnjọ, oṣu keje.

Ọmọ ẹgbọn Aragbiji ti ilu Iragbiji, Ọba Abdulrasheed Ayọtunde Ọlabomi, ni Saheed, ṣugbọn ilu Oṣogbo lo n gbe.

O ni iyawo kan, o si bimọ meji. Ileewe Poli ipinlẹ Kwara lo ti kẹkọọ pari, ko to bẹrẹ ka-ra-ka-ta niluu Oṣogbo. Ọmọ ọdun mejidinlọgbọn ni ko too pade iku ojiji nirọlẹ ọjọ naa.

Leave a Reply