Aderohunmu Kazeem
Ileeṣẹ LCC, iyẹn ileeṣẹ to n mojuto too geeti Lẹkki, nibi ti wahala ti ṣẹlẹ nijọsi, ti gbe fidio aṣiri ti wọn maa n gbe si awọn ibi kọlọfin kan lati mọ awọn ohun to n lọ tabi ohun to ba ṣẹlẹ fun igbimọ oluwadii to n ṣiṣẹ lori iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Lẹkki, nibi tawọn ṣọja ti yinbọn lu awọn ọdọ to n ṣewọde SARS nibi ti wọn kora jọ si jẹẹjẹ wọn logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Ọga agba ileeṣẹ naa, Abayọmi Ọmọmuwa, fun igbimọ oluwadii ọhun ni fidio yii, to si sọ pe, ‘‘Mo le fidi rẹ mule fun yin pe aworan fidio ikọkọ ta a gbe si awọn ibi kọlọfin lasiko iṣẹlẹ to waye logunjọ, oṣu ọjọ kẹwaa, ọdun yii ni mo gbe wa yii.’’
Bakan naa ni wọn fun igbimọ naa ni atẹjade ti wọn fi sọ pe ko si ootọ ninu ohun ti awọn kan n sọ kiri pe niṣe ni awọn fun awọn ọlọpaa lowo ẹyin lati le fi da iwọde naa ru.