Ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori oku Kabiru ti wọn ba lorita Ọkinni, nipinlẹ Ọṣun

Florence Babaṣọla

 

 

 

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iku ọmọkunrin kan ti awọn eeyan ilu Ọkinni, nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ, ba lorita ilu naa nidaaji ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ṣe lawọn araalu deede ba oku ọkunrin ti wọn pe ni Kabiru naa ninu agbara ẹjẹ, ti ko si sẹni to mọ bo ṣe debẹ tabi ibi to ti n bọ.

ALAROYE gbọ pe oju ibọn wa lara ọmọ bibi ilu Ilobu, nitosi ilu Ọkinni, ọhun, eleyii to fi han pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ibọn ni wọn fi pa a.

Kia ni wọn lọọ fi ọrọ naa to ọlọpaa agbegbe naa leti, ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa fẹẹ gbe oku rẹ lawọn mọlẹbi rẹ sọ pe awọn ko le yọnda rẹ fun wọn, nitori awọn gbọdọ sin in nilana ẹsin Musulumi.

Ọpalọla ṣalaye pe gbogbo atotonu awọn ọlọpaa pe ki wọn gbe oku Kabiru lọ fun ayẹwo nileewosan lati le mọ nnkan to ṣeku pa a ni awọn mọlẹbi rẹ ko gba.

Alukoro sọ siwaju pe awọn ọlọpaa ti duro wamuwamu lagbegbe naa lati le dena wahala ti ẹnikẹni ba fẹẹ da silẹ latari iku Kabiru, ati lati tuṣu desalẹ ikoko ohun to ṣokunfa iku rẹ.

Leave a Reply