Ọlọpaa ti mu meji lara awọn janduku to fajọngbọn l’Ebute-Mẹta

Faith Adebọla, Eko      

Latari bawọn janduku kan ṣe da wahala silẹ l’Opopona Herbert Macauly, lagbegbe Ebute-Mẹta, ni Yaba, ipinlẹ Eko, lọsan-an Ọjọbọ, Wẹsidee yii, ileeṣẹ ọlọpaa lawọn ti bomi pana rukerudo ọhun, ọwọ awọn si ti ba meji lara awọn ewele ọmọ to dana ijọngbọn ọhun, iyẹn Tunde Rosanye, ẹni ọdun mọkandinlogoji, ati Muyideen Ayede, ẹni ogun ọdun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko to sọrọ nipa iṣẹlẹ yii f’ALAROYE ninu atẹjade kan sọ pe lara awọn nnkan ija ti wọn ri gba lọwọ awọn afurasi ọdaran ọhun ni ibọn ibilẹ kan, awọn katiriiji ọta ibọn ti wọn ti yin ateyi ti wọn o ti i yin, ada meji, ọbẹ mẹta, foonu alagbeeka kan ati baagi kekere kan ti wọn fi nko awọn nnkan ija kiri.

O ni kawọn ọlọpaa too debi iṣẹlẹ ọhun, awọn ọmọ iṣọta yii ti n da awọn eeyan lọna, wọn n gba awọn dukia wọn bii foonu, ṣeeni ọrun ati owo, eyi si mu kawọn araalu ko ọkan soke, ti wọn n sa kijokijo.

Ipe tawọn ọlọpaa gba lori aago wọn leralera lo mu ki wọn tete yọju sibi iṣẹlẹ ọhun, bawọn ọmọ ganfe naa si ṣe ri mọto ọlọpaa ni wọn fẹsẹ fẹ ẹ.

Ni bayii, Adejọbi lawọn ọtẹlẹmuyẹ ti wa laarin igboro lagbegbe naa, wọn n fimu finlẹ lati wa awọn to sa lọ nibikibi ti wọn ba mori mu si.

O lawọn meji tọwọ ba yii ti balẹ sahaamọ ẹka ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, wọn ti n ran awọn agbofinro lọwọ lẹnu iṣẹ iwadii wọn, ko si ni i pẹ ti wọn maa foju wọn bale-ẹjọ, gẹgẹ bi aṣẹ ti Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, pa.

Leave a Reply