Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Iroyin to n tẹ ALAROYE lọwọ bayii ti fidii rẹ mulẹ pe olu ileeṣẹ ọlọpaa lorileede yii ti kọwe si Kọmiṣanna ọlọpaa Ọṣun, Ọlawale Ọlọkọde, lati taari iwadii lori iku to pa akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, si Abuja.
Aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, la gbọ pe lẹta naa de si Oṣogbo, ninu eyi ti wọn ti paṣẹ pe ki wọn maa gbe alaga ileetura Hilton, niluu Ileefẹ, nibi ti Timothy ku si, Dokita Ramon Adedoyin, atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa mi-in ti wọn mu lori ẹsun naa bọ l’Abuja.
Ọjọ keje, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni Timothy gba yara nileetura naa, nigba to waa ṣedanwo ifimọ-kunmọ (MBA) rẹ ni ẹka Fasiti Ifẹ to wa niluu Moro, nipinlẹ Ọṣun, to si di awati lati ọjọ naa.
Nigba ti iwadii fi han pe otẹẹli naa lo sun ni awọn ọlọpaa ko mẹfa lara awọn oṣiṣẹ ibẹ, ninu eyi ti akọwe ti Timothy san owo ọjọ meji sinu akanti rẹ wa.
Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii kan naa ni wọn ri oku Timothy nibi ti wọn sin in si loju ọna Ifẹ si Ibadan, wọn si fi pampẹ ọba gbe Dokita Ramon Adedoyin, ti wọn si n wa ọmọ rẹ to jẹ alakooso ileetura naa bayii.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn dokita ṣe iwadii si oku Timothy nileewosan UNIOSUNTHC to wa niluu Oṣogbo, esi iwadii wọn ko si ti i jade.
Amọ sa, ALAROYE gbọ pe o ṣee ṣe ki wọn ko awọn afurasi naa kuro l’Oṣogbo lọ si Abuja lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, tabi laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide.