Awọn aṣofin ilẹ wa ti buwọ lu aba eto isuna owo ti Naijiria yoo na lọdun 2021 ta a fẹẹ mu yii. Tiriliọnu mẹtala ati ẹgbẹta naira din diẹ (N13.588 trillion) ni wọn fọwọ si.
Ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ni ile-aṣofin mejeeji faṣẹ si aba naa, wọn si pinnu lati fi i ṣọwọ si Aarẹ Muhammadu Buhari lati fọwọ si i, ki eto iṣuna naa le bẹrẹ iṣẹ.
Ninu aba naa, owo to fẹrẹ to ẹgbẹta miliọnu lawọn aṣofin naa tun fi kun iyẹ tijọba gbe siwaju wọn lati yẹ wo. Tiriliọnu mẹtala ati mejilelọgọrin naira (N13.082 trillion) ni Buhari gbe kalẹ niwaju wọn lọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa yii, ṣugbọn tiriliọnu mẹtala ati ẹgbẹta naira din diẹ (N13.588 trillion) lawọn aṣofin naa panu-pọ le lori, oun si ni wọn fọwọ si lọjọ Aje.
Wọn ni bọjẹẹti ti wọn pe akọle ẹ ni ‘Amusọji ọrọ-aje’ naa maa jẹ ki ọrọ-aje Naijiria sunwọn si i, o maa jẹ ki a wo awọn ọna mi-in ti owo le gba wọle yatọ si ti epo rọbi, o si maa din iṣẹ ati inira to n ba awọn araalu finra ku gan-an.
Nnkan bii tiriliọnu mẹta aabọ ni wọn yoo fi san pada ninu awọn gbese ti orileede wa jẹ, tiriliọnu mẹrin o le diẹ lo maa ba iṣẹ ilu ati awọn ohun amayedẹrun lọ, nigba ti tiriliọnu marun-un aabọ maa lọ sori awọn owo-oṣu ati ajẹmọnu gbogbo.
Iṣiro ogoji owo dọla Amẹrika fun agba epo kan ni wọn lawọn fi ṣiro aba eto iṣuna naa.
Awọn aṣofin naa ni tijọba ba buwọ lu u, ti wọn si tẹle e, nile loko lafẹfẹ igbe aye ọtun yoo fẹ de lorileede yii.