Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn agba bọ, wọn ni bi iku ile ko ba pa ni, tode ko le ri ni pa. Owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu ọkunrin ọlọdẹ kan, Abiọdun Osuntimẹhin, ẹni to gbimọ pọ pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ kan lati digun ja ileepo ti wọn ni ko maa ṣọ lole
Awọn adigunjale kan ni wọn ya bo ileepo S. A to wa niluu Ondo, lalẹ ọjọ kejidinlọgbọn, osu keji, ọdun ta wa yii, nibi ti wọn ti yinbọn pa ọkan ninu awọn oṣiṣẹ alaabo to n ṣọ ibẹ, ti wọn si tun ji owo to to bii miliọnu meji naira gbe sa lọ.
Ninu alaye ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Bọlaji Salami, ṣe fun akọroyin wa, o ni alẹ ọjọ ti iṣẹlẹ ọhun waye lawọn agbofinro tí fi pampẹ ofin gbe Abiọdun toun naa jẹ ọkan lara awọn ọlọdẹ to n ṣọ ileepo ọhun lọ si tesan fun ifọrọwanilẹnuwo.
Lẹyin ọpọlọpọ iwadii lo ni afurasi ọhun jẹwọ ipa to ko ninu iṣẹlẹ idigunjale naa.