Ileewe awọn ọlọpaa ni Babangida atawọn ẹgbẹ ẹ ti lọọ jale

Faith Adebọla, Eko

Pako bii maaluu to r’ọbẹ lọwọ alapata lawọn afurasi ọdaran mẹrin kan n wo nigba ti wọn dewaju adajọ laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee yii, ẹsun ile fifọ ati ole jija ni wọn fi kan wọn, tori ẹ ni wọn ṣe dele-ẹjọ.

Orukọ awọn mẹrẹẹrin ni Jerry Andrew, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, Ahmed Babangida, ẹni ogun ọdun, Abdulrahman Supi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn. Ẹni kẹrin wọn ni Saliu Muhammed, ẹni ọdun marundinlogoji ni.

Nigba ti wọn pe ẹjọ wọn ni kootu Majisreeti ki-in-ni to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, Agbefọba Inpẹkitọ Emmanuel Ajayi, ṣalaye fun kootu pe ogbologboo fọlefọle lawọn afurasi ọdaran mẹrin naa, o ni lọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji to kọja yii, ni wọn lọọ fo iganna wọ ọgba ileewe  awọn ọlọpaa to wa ni agbegbe Ikẹja, ni nnkan bii aago mejila aabọ oru.

Awọn windo alumi (aluminium windows) to jẹ tijọba, ti wọn yọ kuro nigba ti wọn n ṣatunṣe si awọn ile kan ninu ileewe ọhun, atawọn gilaasi windo naa ti wọn ko jọ sẹgbẹẹ kan ninu ọgba naa ni wọn lawọn olujẹjọ naa ji ko. Wọn tun ji faanu meji, timutimu nla meji,

 

Ibi ti wọn ti n gbiyanju ati ko awọn ẹru naa jade lọwọ ti ba wọn, tawọn agbofinro fi ka wọn mọ, ti wọn fi dero ahamọ ọlọpaa, ki wọn too taari wọn sile-ẹjọ.

Ẹsun ile fifọ ati ole jija ti wọn fi kan wọn naa lo ni o ta ko isọri ọrinlerugba ati meje, ọọdunrun ati meje, ati isọri irinwo o le mọkanla ninu iwe ofin iwa ọdaran tọdun 2015 nipinlẹ Eko.

Nigba ti wọn bi wọn leere boya wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi, awọn olujẹjọ naa lawọn ko jẹbi pẹlu alaye.

Adajọ A. S. Odusanya ni ki wọn ma ti i ṣalaye, o ni ki wọn ṣi pada sahaamọ awọn ọlọpaa tabi ki wọn gba beeli ẹnikọọkan wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira, ati ẹlẹrii meji meji ti ọkọọkan wọn ni iye owo kan naa, ti wọn si ni dukia to ṣee tọka si laduugbo kootu naa.

Odusanya loun sun igbẹjọ ati alaye wọn si ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹta.

Leave a Reply