Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lọjọ Satide, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ni ọwọ ba gende-kunrin yii, Imọlẹayọ Adekọya, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33), to fi ipa ba ọmọbinrin kan to n lọ jẹẹjẹ ẹ lo pọ ni Sagamu, to ṣe e tan, to waa ni ẹjọ oun naa kọ, oun mu ọti yo ni.
Teṣan ọlọpaa Sakora, ni Ṣagamu, lọmọbinrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) to ṣe ‘kinni’ fun ti lọọ fẹjọ sun.
Obinrin naa ṣalaye fawọn ọlọpaa pe oun n bọ lati agbegbe Ipoju ni, oun si pade ọkunrin yii lọna, iyẹn Imọlẹ.
O ni bo ṣe ri oun lo ni ṣe oun o le ki eeyan, abi, ọmọbinrin naa ni oun sọ fun un pe ko ma binu, oun ko mọ ọn ri loun ko ṣe ki i.
O ni si iyalẹnu oun, niṣe ni ọkunrin naa bẹrẹ si i lu oun, to si wọ oun lọ si ẹyin ile rẹ, nibi to ti faṣọ ya mọ oun lara, to si fipa ba oun lo pọ. Gbogbo ariwo toun n pa ko tilẹ jọ ọ loju, afigba to fipa wọle soun lara.
Ọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri naa lọọ sọ ohun to ṣẹlẹ fun baba rẹ nile, oun ati baba naa ni wọn si jọ pada lọọ ṣalaye ni teṣan, ti wọn fi lọọ mu Imọlẹayọ to fipa ṣe ‘kinni’ fun ọmọ ọlọmọ.
Nigba to n jẹwọ ẹṣẹ ẹ fawọn ọlọpaa, Imọlẹ sọ pe loootọ loun ṣe gbogbo ohun ti ọmọ naa sọ pe oun ṣe pẹlu ẹ, o ni ṣugbọn ẹjọ oun naa kọ, oun ti muti yo lasiko yẹn ni.
O ni Gbogbo boun ṣe n ku u bii ẹni ku elubọ to, oun ko mọ rara.
Niṣe ni wọn mu ọmọ to ba sun lọ sọsibitu fun itọju, ki wọn si le mọ abajade ibasun naa lara rẹ.
Bẹẹ ni CP Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn gbe Imọlẹayọ lọ sẹka SCID, nibi ti wọn ti n tọpinpin iwa ọdaran gbogbo.