Ina ẹlẹntiriiki to ja gbẹmi iya, awọn ọmọ ẹ wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun

Monisọla Saka

Ina ẹlẹntiriiki to ṣẹ yọ nibi ẹrọ amunawa tiransifọma to wa ninu ọja kan niluu Mowe, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ti ṣe bẹẹ sọ awọn mọlẹbi kan sinu ipayinkeke, pẹlu bo ṣe gbẹmi Arabinrin Ujunwa Okechukwuma, tawọn ọmọ rẹ meji, Louis ati Onyinyechi, si wa lẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun lọsibitu ti wọn ti n tọju wọn.

Yatọ si iya atawọn ọmọ ẹ meji yii, awọn eeyan mi-in ti ijamba ina mọnamọna yii tun ṣọṣẹ fun, ti wọn si fara pa yannayanna ni Shuaib Saheed, Zainab Babatunde, ati Okiki Azeez.

Alaye tawọn eeyan agbegbe naa ṣe ni pe eeyan mẹta, to fi mọ alaboyun kan, lo ku, amọ ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fidi ẹ mulẹ pe Arabinrin Okechukwuma nikan lo gbabẹ ku, tawọn marun-un yooku, titi kan ọmọ oloogbe, ṣi wa nibi ti wọn ti n gba itọju.

Ṣaaju iṣẹlẹ naa ni wọn ti ni awọn ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna laduugbo naa, Ibadan Electricity Distribution Company (IBEDC), ti kilọ fawọn to ni ṣọọbu lawọn ibi ti waya ina gba kọja atawọn ṣọọbu ti waya ina ti ja bọ lu lori latari afẹfẹ ojo to rọ nibẹ laipẹ yii lati ṣọra, nitori ewu to wa ninu ki waya ina ja lulẹ lojiji, ki wọn si kuro ni agbegbe ibẹ.

O ṣalaye siwaju si i pe ọgbọn tawọn oniṣọọbu n da si aaye ti wọn fun wọn, ti wọn si n ṣe bẹẹ fa ṣọọbu wọn gun sọwọ iwaju, debi tawọn opo ina alagbara to muna wọ’nu adugbo naa wa le ṣokunfa ijamba ina mọnamọna.

Ojo alatẹgun nla to rọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin yii, lo mu kawọn waya ina ja bọ sori ṣọọbu ọhun.

Atẹgun ojo nla to wo awọn opo ina ati waya to ja lulẹ ni wọn ni awọn oniṣẹ mọnamọna waa tun ṣe. Ko pẹ pupọ lẹyin naa ni ina pada de, ṣugbọn awọn opo ina ti waya wọn ṣi tutu tun wo. Iyalẹnu lo jẹ fawọn eeyan naa bi ina ṣe tun bẹrẹ si i ṣẹ lara waya, iṣẹlẹ yii lo mu ẹmi eeyan lọ, ti ọpọ si wa nileeewosan.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe obinrin kan ku, awọn ọmọ ẹ meji si n gba itọju lọwọ lọsibitu. O fi kun un pe awọn mẹta mi-in naa fara pa yannayanna, awọn naa si ti wa nileewosan.

O ṣalaye siwaju pe awọn eekan ninu adugbo naa ti jokoo ipade lati wa ọna abayọ si gbogbo awọn to muna lọna aitọ kaakiri inu ọja.

Leave a Reply