INEC kede ọjọ ti idibo gomina yoo waye l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ajọ eleto idibo orileede yii, INEC, ti kede pe ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, ọdun 2022, ni idibo gomina yoo waye nipinlẹ Ọṣun.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe ajọ naa, Rose Oriaran-Anthony, fi sita lo ti ṣalaye pe igbesẹ naa wa nibaamu pẹlu ipin kin-in-ni ati ikeji abala ikejidinlọgọsan-an o din meji ofin eto idibo orileede yii to sọ pe idibo gbọdọ waye nigba to ba ku aadọjọ ọjọ ti asiko ẹni to wa lori ipo yoo wa sopin.

Anthony fi kun ọrọ rẹ pe aarin ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, si ọjọ kejila, oṣu kẹta, ọdun 2022, ni idibo abẹle gbọdọ waye ninu awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn ba fẹẹ kopa ninu idibo gomina l’Ọṣun.

O ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2022, ni ipolongo idibo yoo bẹrẹ, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹfa, si ni ajọ INEC yoo gbe orukọ awọn oludije jade.

Ọjọ kẹrinla, oṣu keje, ọdun 2022, ni gbogbo ipolongo eto idibo gbọdọ wa sopin, nigba ti idibo yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje.

Leave a Reply