Inu ẹjẹ lole ti mo n ja yii wa, ọkada mẹfa ni mo ti ji kawọn Amọtẹkun too mu mi-Shittu

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọwọ awọn agbofinro ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ, ti tẹ mẹkaniiki ọkada to maa n ji ọkada gbe niluu Okeho, nijọba ibilẹ Kajọla, nipinlẹ Ọyọ.

Maṣinni ti awọn ọlọkada ba paaki silẹ jẹẹjẹ ni wọn lọkunrin ẹni ogoji (40) ọdun naa maa n ji gbe bo ti wu ki wọn fi kọkọrọ ti i pa to. Ṣe mẹko to n tun okada ṣe ni, gbogbo tifun-tẹdọ ara alupupu lo mọ.

ALAROYE gbọ pe o pẹ ti Ibraheem ti maa n ṣiṣẹ ibi naa, to jẹ pe bo ṣe n ba awọn ọlọkada tun alupupu wọn ṣe naa lo tun maa n ji i gbe nibi ti wọn ba paaki rẹ si.

Nigba to n jẹwọ ẹṣẹ rẹ fun akọroyin wa n’Ibadan, Ibraheem ṣalaye pe, “Nitori pe mo gbe ọkada lawọn Amọtẹkun ṣe mu mi. Bi mo ṣe maa n ri okada ji ni pe ti wọn ba ti gbe maṣinni naa silẹ, emi aa lọ sibẹ, ma a yọ waya rẹ. Emi nikan ni mo si maa n da ṣiṣẹ yii.

“Ọkada mẹfa ni mo ti gbe, mo si ti ta mẹta ninu ẹ, ki i ṣe pe mo ta wọn lodidi o, mo n yọ paati ara wọn kalẹ lọkọọkan ta ni.

Mo rẹdi lati pa iṣẹ yii ti, ti mo ba tun ṣeru ẹ, ki wọn bẹ ori mi fun Ogun tabi ki wọn yin mi nibọn”.

Njẹ ki lo sun ọ dedii ole jija nigba too niṣẹ lọwọ, ọkunrin ẹni ogoji (40) ọdun yii fesi, o ni, “Ka ṣaa sọ pe inu ẹjẹ mi lole ti mo n ja yii wa, ṣugbọn nigba ti ọwọ ti tẹ mi yii, ti wọn ba tun gba mi mu nidii ole jija, ki wọn pa mi”.

Iyẹn ni pe awọn kan ti n jale nidile yin ṣaaju, ọga mẹko ti ki i ri maṣinni soju yii tun fesi, o ni, “O jọ bẹẹ. O ṣẹlẹ bẹẹ. O pọsibu ko jẹ afiṣe’’.

Nigba ti akọroyin wa beere boya o le fi iṣẹ naa le ọmọ lọwọ, Ibraheem ni, ‘‘Mo ti bimọ, ṣugbọn emi o le fi iṣẹ ole le ọmọ temi lọwọ. Mo ti ba ara mi lorukọ jẹ, mo ti ba idile mi paapaa lorukọ jẹ.

‘‘Ninu ọkada mẹfa ti mo ji, mo ti ta mẹta nibẹ, mo gbe meji pamọ, pe ki n le ri wọn ta lọjọ iwaju, mo n gun ọkan yooku kiri.

“Mo ṣẹṣẹ bẹrẹ ole jija naa ni. Bi gbogbo ilu Okeho ṣe tobi to, ko sẹni to le sọ pe mo gbe nnkan oun ri, afi nigba kan bayii ti mo gbe owo ẹgbọn mi, ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (₦500, 000)’’.

Ọkan ninu awọn ti Ibraheem ji ọkada wọn gbe, Ọgbẹni Adedeji Saheed, sọ pe niwaju ṣọọbu iyawo oun loun paaki alupupu oun si lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ti ọga mẹko fi ji i gbe.

Ọkunrin to pera ẹ lawakọ ero yii ṣalaye pe, “Mo fẹẹ lọọ fi ọkada yẹn gbe iyawo mi lọ sile ni. Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ni mo debẹ, mo si paaki ọkada mi siwaju ṣọọbu iyawo mi. Mo kan jade lasan, pe ki n de, ka waa maa lọ sile ni o, afi bi mo ṣe de ti mi o ba ọkada nibi ti mo paaki ẹ si mọ. Bi mo ṣe lọọ fi to awọn Amọtẹkun leti niyẹn.

“Lọsẹ to kọja lawọn Amọtẹkun pe mi pe ki n waa wo ọkada mi pẹlu ẹri. Mo si ri i pe ọkada mi ni loootọ.

Ọgbẹni Salawu Fatai Ọdẹyẹmi, ẹni ti jagunlabi ji alupupu tiẹ naa ṣalaye pe, “Ara mi ko ya ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii. Wọn fi maṣinni gbe mi lọ sileewosan ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ. Ba a ṣe dele ni mo sun. Nigba to di ọwọ alẹ ti mo ni ki n lọọ gbe maṣinni nibi to wa lo di pe mi o ri i mọ.

‘‘A lọọ fi ẹjọ sun awọn Amọtẹkun pe wọn ma ti ji ọkada mi gbe. Nigba to di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, lawọn Amọtẹkun pe mi pe awọn ti ba mi ri ọkada mi. Mo dupẹ gidi lọwọ awọn Amọtẹkun nitori iṣẹ ribiribi ni wọn ṣe”.

Gẹgẹ bi igbakeji ọga agba awọn Amọtẹkun ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Akinro Kazeem Babalọla, ṣe ṣalaye fakọroyin wa, O ni lati ọdun to kọja lawọn ti gbọ iroyin nipa bi ọkunrin to n jẹ Shittu Ibraheem yii ṣe maa n ji ọkada, tawọn si ti n wa a, ki ọwọ too tẹ ẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja.

‘‘Nigba ta a kọkọ lọọ ba a, o loun ki i ṣole, mẹkaniiki ọkada loun. A waa fi ẹnikan ṣọ ọ titi ta a fi ri i gba mu lọrun ọwọ lọjọ Tusidee to kọja.

‘‘Odidi ọkada mẹta la ba lọwọ ẹ pẹlu ọpọlọpọ paati awọn ọkada mi-in to ti tu palẹ. Awọn paati yẹn lo n ta lọkọọkan. A ti ṣewadii tiwa, ohun to ku bayii ni ka fa a le awọn ọlọpaa lọwọ fun igbesẹ to ba tun yẹ. A ti ri awọn to ni awọn ọkada wọnyẹn, a si maa da ti kaluku pada fun un ni kete ta a ba pari gbogbo eto to yẹ lori iṣẹlẹ yii.

 

Leave a Reply