Ọdun mẹsan-an sẹyin ni emi ati Sanyẹri ti kọra wa silẹ-Ọmọlara

Jọkẹ Amọri

Ha-in lọpọ awọn to gbọ ohun ti Ọmọlara Jimoh, iyawo ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Afọnja Ọlaniyi, ti gbogbo eeyan mọ si Sanyẹri kọ sori ikanni Instagraamu rẹ pe lati ọdun mẹsan-an sẹyin loun ati oṣere ilẹ wa to jẹ ọmọ bibi ilu Ọyọ naa ko ti fẹra awọn mọ. O ni loootọ lawọn ko jọ wa bii lọko-laya mọ, ṣugbọn awọn jọ n tọju ọmọ awọn ni, nitori bo ṣe n ṣe ojuṣe rẹ lori awọn ọmọ loun naa n ṣe toun.

Ohun to mu kọrọ ipinya tọkọ-tiyawo naa ya awọn eeyan lẹnu ni pe ko si ẹni to gbọ ija wọn ti tẹlẹ, bẹẹ ni wọn ko si pariwo ipinya naa rara. Bi ko si je ti obinrin naa to gbe ọrọ yii sori Instagraamu rẹ, ko sẹni to maa mọ bo ṣe n lọ, nitori gbogbo igba ti ọkunrin yii ba n ṣe ọjọọbi lawọn ọmọ rẹ maa n ṣe fidio, ti wọn aa fi ki i daaaa, ti wọn yoo si sọ ọrọ iwuri nipa baba wọn yii.

Sugbọn lojiji ni iyawo Sanyẹri telẹ yii gbe ọrọ naa jade lorin ayelujara pẹlu fọto oun ati oṣere naa pe ‘‘Si gbogbo eeyan, eyi ni lati ṣalaye nipa aṣigbọ nipa igbeyawo mi ati igbe aye mi ti mi o gbe sita gbangba. Awọn eeyan ni lati ṣọra gidigidi ki wọn too maa dajọ. Awọn agbalagba meji, paapaa ju lọ, awọn meji ti wọn ti bimọ fun ara wọn ti wọn ba pinnu lati maa gbe igbe aye alaafia pẹlu ara wọn nitori ti awọn ọmọ wọn. Ki i ṣe pe wọn ko mọ ohun ti wọn n ṣe, ki i si i ṣe gbogbo eeyan naa lo maa n fẹẹ pe awọn oniroyin si ohun to n ṣẹlẹ labẹ orule wọn, nitori eyi, ki iru awọn eeyan bẹẹ ṣọgba wọn.

‘‘Ohun ti mo n sọ ni pe ki i ṣe ohun to rọrun pe mo jẹ ẹni ti ko lọkọ lati bii ọdun mẹsan-an ṣeyin, to si jẹ pe emi ati ọkọ mi atijọ naa la jọ n tọju awọn ọmọ wa ko rọrun rara. Fun awa mejeeji, bo tilẹ jẹ pe a ko gbe ni orileede kan naa mọ, pẹlu ẹ naa, mo si n ṣe daadaa ninu ojuṣe mi gegẹ bii obinrin ti ko si nile ọkọ ati obinrin to ni ọmọ, oun naa si n ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bii baba si awọn ọmọ. To ba jẹ pe ohun gbogbo ti mo ti sọ yii ko kan yin, ẹ ma gbe iyẹn wa sibi o. Mi o ni i fara mọ ki ẹnikẹni maa da si ọrọ nipa igbesi aye mi ti mo rọra n gbe labẹ orule mi. Ki n waa ni inu didun ya mi lara ju ere awada kankan lọ, bi mo si ṣe fẹ ko ri niyẹn. Ẹ ṣeun. Orukọ mi ni ỌMỌLARA ỌLAIYA JIMOH.’’

Bi ọmọbinrin naa ṣe kọ ọ sori ikanni rẹ niyi.

Ojiji ni ọrọ naa ba ọpọ eeyan, bẹẹ lawọn ololufẹ ọkunrin yii ko si le gba eti wọn gbọ pe oun ati ọmọbinrin ti wọn jọ ṣegbeyawo  alarinrin lọdun diẹ ti pin gaari.

Ninu ifọrọwerọ kan ti Ọlaniyi Afọnja ṣe ni ọdun diẹ sẹyin lo ti ṣalaye pe ọdun 2004, nigba ti oun lọọ ṣafihan fiimu oun kan, ‘Ọkan Ẹmi’  loun pade iyawo oun yii, ti oun si dẹnu ifẹ kọ ọ.

Leave a Reply