Inu mọto tawọn ọmọ iya mẹta ti n ṣere looru mu wọn pa si l’Ekoo

Ere ni awọn ọmọ iya mẹta kan tọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹta si mẹjọ n ṣe ninu ọkọ kan ti wọn paaki sita lagbegbe Owode Elede, niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko. Inu ọkọ naa ni ooru mu wọn pa si.
Gẹgẹ bi akọroyin The Nation ṣe ṣalaye, awọn ọmọ mẹtẹẹta ọhun ni: Oliseh, to jẹ ọmọ ọdun mẹta, Daniel, to jẹ ẹgbọn jẹ ọmọ ọdun mẹfa, nigba ti Destiny Egba, to jẹ ẹgbọn patapata fun wọn jẹ ọmọ ọdun mẹjọ. Awọn mẹtẹẹta yii ni wọn sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ airibi mi atẹgun simu pẹlu bi wọn ṣe ti ara wọn mọnu ọkọ naa ti wọn ko si rẹni ba wọn ṣilẹkun ọkọ ọhun lo pa wọn nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọhun.

Inu ọkọ HYUNDAI ti nọmba rẹ jẹ BDG404CL, ti wọn paaki kalẹ ni awọn ọmọ naa ko si, ti wọn n ṣere ni tiwọn l’Ojule kẹrindinlogun, adugbo Gbamire, Owode Elede, n’Ikorodu, ti wọn o si rọna jade ninu mọto naa mọ.
si.
Ohun ti ko waa ye ẹnikẹni ni iye wakati ati igba ti awọn ọmọ naa lo ninu ọkọ ọhun ki awọn alejo kan to wa ẹni to ni mọto naa wa too ṣakiyesi pe awọn eeyan kan wa ninu ọkọ naa.
Iya awọn ọmọ naa, Lorita Azibato, ko ti i de lati ọja nigba ti wọn gbe oku awọn ọmọ naa jade ninu ọkọ ni nnkan bii aago meje alẹ, awọn aladuugbo atawọn alabaagbelepọ rẹ o si ni nọmba foonu rẹ lati le pe e pe ko maa bọ nile, eyi lo mu ki awọn ọlọpaa duro titi ti arabinrin naa fi dari wale ni nnkan bii aago mọkanla aabọ alẹ, ti wọn fi tufọ iku awọn ọmọ ẹ fun un.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundenyin sọ pe awọn agbofinro to wa lagbegbe Owode Onirin ni wọn fi ọrọ naa to leti ni nnkan bii aago meje alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, pe wọn ri oku awọn ọmọde kan ti wọn jẹ ọmọ iya, ọmọ baba kan naa, ninu ọkọ.
O ni lọgan lawọn ọtẹlẹmuyẹ ti debẹ, wọn ṣe awọn iwadii kan, wọn si gbe awọn oku naa jade ninu mọto lọ si mọṣuari.

Leave a Reply