Inu oko ti Amaka ti n ṣiṣẹ lawọn Fulani ka a mọ, wọn si ṣa a ladaa yannayanna

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Obinrin kan, Amaka Okafor, lawọn Fulani tun lọọ ba ninu oko rẹ niluu Ọgbẹṣẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ti wọn si kun un bii ẹni kun ẹran.

Oludamọran agba fun gomina lori ọrọ eto ọgbin, Akin Olotu, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun akọroyin wa ni ibi ti obinrin naa ti n ṣiṣẹ lọwọ ninu oko irẹsi to gbin lawọn darandaran ọhun lọọ ka a mọ.

O ni gbogbo ara rẹ ni wọn fi ada ṣa yannayanna ki wọn too fi i silẹ ninu agbara ẹjẹ lẹyin ti wọn ro pe o ti ku.

Olotu ni obinrin ti wọn ṣe leṣe naa ṣi wa nile-iwosan kan to ti n gba itọju lọwọ.

Leave a Reply