Jide Alabi
Olori ikọ ọwọ kọkanlelọgọrin awọn ọmọ ogun ọtelẹmuyẹ ninu iṣẹ ṣọja to wa niluu Eko, Brigedia Ahmed Taiwo, ti binu si Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu. Ọkunrin ṣọja naa ni inu oun ko dun si gomina naa pẹlu bo ṣe kọkọ purọ pe oun kọ loun ranṣẹ pe awọn lasiko rogbodiyan SARS to waye ninu oṣu kẹwaa, ọdun yii.
O ni, ‘Sanwo-Olu lo ranṣẹ si wa, o ni apa awọn ọlọpaa ko ka ọrọ naa mọ’
Taiwo sọrọ yii lasiko to fara han niwaju igbimọ to n gbọ ẹjọ ifiyajẹni awọn SARS ati iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Lẹkki, nibi ti awọn ṣọja ti yinbọn mọ awọn ọdọ to n ṣewọde, eyi to si pada ja si wahala gidi, leyii ti ọpọ ẹmi ati dukia si ṣofo.
Bẹ o ba gbagbe, ni kete ti iṣẹlẹ ogunjọ, oṣu kẹwaa, naa waye, ti okiki si kan pe awọn ṣọja yinbọn pa awọn ọdọ to n ṣewọde ni Lẹkki ni Gomina Sanwo-Olu ti jade, to si ni oun ko mọ ohunkohun nipa bi awọn ṣọja ṣe lọ sibi iwọde naa, o ni awọn kan to lagbara ju oun lọ lo wa nidii ọrọ naa.
Afi bi aṣiri ọrọ naa ṣe pada tu pe oun lo ranṣẹ pe awọn ṣọja pe ki wọn waa tu awọn ọdọ naa ka, eyi to pada di rogbodiyan nla pẹlu bi awọn araalu ṣe fi ẹhonu han lori ọrọ Lẹkki naa.
Ọrọ ti gomina yii sọ naa lọga ṣọja yii ni ko dun mọ awọn ninu pẹlu bo ṣe purọ pe oun ko ran awọn niṣẹ.