Inira nla ni afikun owo-epo yoo ko ba araalu – PDP

Aderohunmu Kazeem

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti rọ Aarẹ Muhammadu Buhari lati tun ero rẹ pa lori afikun tijọba rẹ ṣe si owo-epo bẹntiroolu, eyi ti awọn ileepo kan ti bẹrẹ si i ta ni aadọsan-an naira lati ọjọ Ẹti, Furaidee.

Akọwe ikede egbẹ naa, Kọla Ologbodiyan, to gbẹnu ẹgbe naa sọrọ rọ Aarẹ Buhari lati wa wọrọkọ fi ṣada lori afikun owo-epo bẹntiroolu yii. Ẹgbẹ naa ni yoo nira gidi fun araalu lati maa ra epo naa ni iye ti wọn ṣẹṣẹ fẹẹ maa ta a yii, pẹlu ọrọ aje ilẹ wa ti ko dara ti awọn eeyan ilu n koju lọwọlọwọ yii.

Ologbodiyan ni ṣiṣe afikun owo-epo bayii ki i ṣe ohun to daa, nitori yoo tubọ da kun wahala ati iṣoro ti awọn araalu n koju ni. O ni igbesẹ naa da bii ki eeyan tun di ajaga kun ọrọ aje ilẹ wa to ti mẹhẹ telẹ ni.

Ẹgbẹ PDP ni ko yẹ ki ijọba ta jala epo naa ni ọgọrun-un naira, ka ma ti i sọ aadọsan-an naira ti wọn fẹẹ maa ta a bayii. Wọn ni ijọba ko ti i jade sita lati ṣalaye idi pataki ti afikun fi nilati ba epo bentiroolu nilẹ wa.

Ki i ṣe ẹgbẹ oṣelu PDP nikan lo koro oju si igbesẹ ijọba lati fi kun owo-epo yii. Awọn araalu paapaa ti n pariwo, bẹẹ ni wọn n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ inilara ti ijọba gbe naa.

Leave a Reply