Wọn fẹsun kan ọba Ilẹ Oluji, wọn ni kabiyesi ko awọn ọdọ kan jọ fun ẹgbẹ okunkun

Dada Ajikanjẹ

Ọba Ilẹ Oluji, Julius Adetimẹhin, ti sọ pe ko si ootọ ninu iwe ifisun kan ti ẹgbẹ ajafẹtọọ kan kọ si kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ondo pe oun n ko awọn janduku atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun jọ lati maa fi da wahala silẹ.

Ọba alade yii sọ pe ọkan lara awọn eeyan ilu oun lo wa nidii iwe ẹsun ti wọn kọ yii, ati pe ko ṣẹṣẹ maa kọ ọ, bẹẹ loun ko le sọ pato ohun ti ọkunrin naa n fẹ gan-an.

Ninu ẹda iwe ọhun ti ẹgbẹ ajafẹtọọ (Civil Liberties Organization) pin fawọn oniroyin, ti alaga ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Akingbọla Temidayọ, fọwọ si lo ti sọ pe, “Eyi ni lati pe akiyesi ileeṣẹ ọlọpaa si bi Ọba Julius Adetimẹhin, Ọba Ilẹ-Oluji, nijọba ibilẹ Oluji/Oke Igbo, nipinlẹ Ondo, ṣe lẹdi apo pọ pẹlu ọga ọlọpaa teṣan to wa ni llẹ-Oluji ati ọga agbegbe Area ‘H’, lati ko awọn ọdọ kan jọ fun ẹgbẹ okunkun, ti wọn si n ko idaamu ba awọn eeyan agbegbe naa.”

Lara awọn ti wọn sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun n yọ lẹnu lawọn ọlọdẹ ilu naa, ti awọn yẹn ko gba wọn laaye lori bi wọn ṣe n da wahala silẹ lagbegbe ọhun.

Ṣa o, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Ondo, Tee-Leo Ikoro, ti sọ pe ọga ọlọpaa to wa ni Ilẹ-Oluji ati ọga agba to wa ni teṣan Area H, ko le hu iwa to le ko idaamu ba alaafia awujọ. O ni awọn ọga ọlọpaa ti wọn mọ iṣẹ wọn daadaa ni wọn, bẹẹ loun mọ daju pe wọn ko ni i lọwọ si kiko ọmọ ẹgbẹ ọkunkun jọ.

O fi kun un pe to ba jẹ pe loootọ ni wọn ti fi iwe ẹṣun ọhun ṣọwọ, o da oun loju pe, igbesẹ to yẹ yoo waye lori ẹsun naa.

 

Leave a Reply