Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Ọṣun nigba kan to tun jẹ ọkan ninu awọn agbaagba Yoruba Oloye Bisi Akande, ti gbẹnu awọn gomina atawọn oloṣelu yooku sọrọ nibi ipade kan ti wọn ṣe lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, nile ijọba to wa ni Marina, pe ilẹ Yoruba ni ipo aarẹ gbọdọ wa, ko si Yẹkinni kan to gbọdọ yẹ eleyii.
Bakan naa lo sọ pe apejọpọ awọn lọjọ naa fi han pe iṣọkan ni gbogbo awọn wa, lai ka gbogbo awuyewuye to n lọ tabi iye awọn ti wọn ti gba fọọmu lati dije dupo aarẹ nilẹ Yoruba si.
Lẹyin ipade ti wọn ṣe nile ijọba, ni Marina, ni Akande sọrọ lorukọ awọn yooku ti wọn jọ wa nibi ipade ọhun pe iṣọkan wa laarin awọn nilẹ Yoruba, ko si wahala kankan rara, bẹẹ ni ipo aarẹ ko gbọdọ kọja si agbegbe mi-in to ju ilẹ Yoruba lọ.
Ipade to waye fun bii wakati meji ọhun ni Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, Aṣiwaju Bọla Tinubu, Alagba Bisi Akande, Oluṣẹgun Ọṣọba ati gbogbo awọn gomina ilẹ Yoruba wa.
Bakan naa ni awọn gomina tẹlẹ bii Babatunde Raji Faṣọla ti Eko, Niyi Adebayọ lati Ekiti, Ibikunle Amosun lati Ogun, Arẹgbẹṣọla lati ipinlẹ Ọṣun, Akọwe ẹgbẹ APC bayii, Sẹnẹtọ Iyiọla Omiṣore atawọn mi-in peju si.
Lẹyin ipade ọhun ni Bisi Akande ṣalaye ohun ti wọn sọrọ le lori fawọn oniroyin.