Ipade tawọn Tinubu ṣe l’Ekoo yẹn, wọn fakoko ṣofo lasan ni – Fani-Kayọde

Faith Adebọla, Eko

Minisita fun igbokegbodo ọkọ ofurufu ilẹ wa nigba kan, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, ti sọrọ lori ipade awọn agbaagba ẹgbẹ APC nilẹ Yoruba to waye lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niluu Ekoo pe ifakoko ṣofo lasan ni ijokoo ati ipinnu ti wọn lawọn ṣe, reluwee to ti lọ ni wọn n ṣẹwọ si.

Ninu atẹjade kan to fi sori atẹ ayelujara, ni ikanni fesibuuku rẹ, Fani-Kayọde ni ko ni i pẹ mọ ti Bọla Tinubu ati awọn to ko sodi yoo fi mọ pe o lewu keeyan duro de reluwee, adanu nla ni.

O tun ni awọn to ṣepade yii ati ipinnu ti wọn lawọn ṣe ki i ṣe aṣoju Yoruba, wọn o si sọ ero Yoruba jade.

Fani-Kayọde sọ pe “Awọn ti wọn ṣepade l’Ekoo lọjọ Aiku, Sannde yii, ero imọtara-ẹni nikan ati ifẹ ọkan tiwọn ati tẹgbẹ oṣelu wọn ni wọn sọ jade, ki i ṣe ti Yoruba rara.

“Wọn o ṣoju fun Yoruba, bii aadọrin miliọnu ọmọ Yoruba lo wa lagba\ye lonii, Tinubu o ṣoju fun wọn, oun kọ lo si n dari wọn. Iwọnba awọn diẹ kan laarin ẹgbẹ APC ilẹ Yoruba atawọn to jẹ ẹmẹwa ẹ laarin awọn to n ṣejọba lo n dari.

“Ti apero gbogbogboo ba waye nilẹ Yoruba lori boya ka da duro tabi ka ṣi jẹ ara Naijiria, ẹ maa ri i pe bii igba teeyan fulọọṣi igbọnsẹ danu lawọn araalu maa gba awọn eeyan wọnyi danu, wọn maa dẹni ana ninu itan ni.

Tinubu kọ lo nigboro nilẹ Yoruba, awọn to fẹ ki Yoruba da duro lo lero lẹyin, awọn laraalu gba tiwọn.

Ṣe ẹ ri awọn ti wọn ṣepade yii, wọn n ba wọn to fẹẹ ya kuro yii sọrọ labẹlẹ, wọn n ṣatilẹyin fun wọn labẹnu, ṣugbọn wọn o ni i sọ ọ ni gbangba, iwa abosi alakọwe lẹ ri yẹn, ṣeku-ṣẹyẹ ẹlẹnu-meji ni wọn, wọn lójo, wọn o le duro lori ẹsẹ wọn.

Ninu ọkan wọn lọhun-un, o wu wọn ki Yoruba ya kuro lara Naijiria, ka da duro, ṣugbọn kaka ki wọn ṣọkan akin, ki wọn bọ sita sọ ododo ọrọ, ki wọn si jẹ kaye mọ ootọ, odikeji ni wọn n sọ sita, tori wọn fẹ ki Tinubu di aarẹ.”

Leave a Reply