Ipenija eto aabo ti dohun igbagbe lagbegbe Ibarapa- Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ipaniyan, ijinigbe, idigunjale ati iwa ọdaran gbogbo to mu ki eto aabo mẹhẹ lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Ọyọ ti dohun igbagbe.

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lo sọrọ yii nigba to n kopa nibi ayajọ ọdun awọn ibeji lagbaaye, eyi to waye niluu Igboọra, nipinlẹ naa lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja.

Makinde, ẹni to pinnu lati mu idagbasoke ba ilu Igboọra ati agbegbe Ibarapa lapapọ nipasẹ ọdun ibeji yii, ṣeleri lati ṣatunṣe awọn ọna pataki lagbegbe naa.

Gẹgẹ bo ṣe ṣe sọ, “Ohun ta a waa ṣe nibi lonii kọja Odun ibeji. A n fi asiko yii ronu anfaani ti ọdun ibeji le mu wa fun wa ni ipinlẹ Ọyọ, papaaa, nipa irinajo afẹ.

“O ti n lọ bii ọdun mẹrin sẹyin bayii ti mo ti wa sibi waa polongo ibo. Nnkan mẹrin ti mo ṣeleri nigba naa ni eto ìlera, imugbooro eto ọrọ aje ati eto aabo. Inu mi si dun pe gbogbo ileri yẹn ni mo ti mu ṣẹ.

A ni ipenija eto aabo ni ilẹ Ibarapa tẹlẹ, ṣugbọn inu mi dun pe kaluku ti n lọ sibi iṣẹ aje ẹ lalaafia lai si iṣoro eto aabo kankan nibikankan mọ. Ka too dori apere ijọba, ko si nnkan to n jẹ Amọtẹkun, ṣugbọn a dupẹ pe awọn Amọtẹkun lo wa niwaju wa ti wọn n moju to eto aabo yii.

“Ilu Igboọra yii ni ma a ti bẹrẹ ipolongo ibo mi fun idibo ọdun to n bọ. Nitori naa, ẹ máa retí mi pada ni nnkan bii ọsẹ mẹta kan sasiko yii. Ṣugbọn ko too di asiko yẹn, ẹ ti maa ri awọn oṣiṣẹ to maa ṣe oju ọna Ibadan si Eruwa, ati ọna Igboọra si Iganna. Erongba mi ni lati mu idagbasoke eto ọrọ aje ba ilẹ Ibarapa”.

Makinde ni gomina akọkọ ti yoo kopa ninu ajọdun awọn ibeji n’Igboọra.

Gẹgẹ bi awọn to ṣagbekalẹ ajọdun naa, Ọgbẹni Taiwo Ibitoye ati Kẹhinde Ibitoye, ṣe fidi ẹ mulẹ, ” Ki i ṣe Naijiria lorile-ede akọkọ ta a ti maa ṣe ajọdun ibeji ta a maa n ṣe lọdọọdun yii. A ti ṣe e lorileede China, Brazil atawọn orileede mi-in kaakiri agbaye, ṣugbọn ninu gbogbo irin-ajo wa wọnyi, a ri i pe Gomina Makinde ni gomina akọkọ to maa ni ajọṣepọ pẹlu awọn ibejì lagbaaye”.

Nigba ti wọn n ṣalaye pataki ajọdun ọdun yii, eyi ti wọn pe akori ẹ ni ‘‘Bibi Ibeji fun Imugbooro Eto Ọrọ Aje”, Taye ati Kẹhinde Ibitoye sọ pe “A wa nibi lonii lati ṣajọdun ibeji ati lati bu ẹyẹ ikẹyin fun Ọba Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta ti i ṣe Alaafin Ọyọ ti wọn darapọ mọ awọn baba nla wọn laipẹ yii. Aafin wọn la ti maa n ṣe ayẹyẹ yii nigba ta a ṣẹṣẹ bẹrẹ.

“Lọdun to kọja l’Alaafin Ọlayiwọla fi ibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọ bibi inu wọn silẹ lati waa ba wa ṣajọdun ibeji n’Igboọra nibi.

Igboọra lo ni ibeji to pọ ju lagbaaye. Korona ti ba eto ọrọ aje jẹ, idi niyẹn ta a ṣe pinnu lati lo ajọdun ọdun yii lati mu agbega ba eto ọrọ aje ilu yii”.

Wọn waa beere fun atilẹyin Gomina Makinde lori erongba wọn lati ṣe akojọpọ awọn ibeji to pọ kaakiri agbaye lati waa kopa ninu ajọdun ọdun to n bọ, ki eto ọhun le jẹ aaye akọkọ lorilẹ aye ti awọn ibeji to pọ ju lọ yoo ti ko ara wọn jọ soju kan naa, ki kinni ọhun le wọnu iwe itan agbaye ti wọn n pe ni Guiness Book of Records.

Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi wa lara awọn ọba to kopa nibi eto naa pẹlu bo ṣe ran Salu ti Ẹdun-Abọn, Ọba Adesọji Ọlatunde Kẹhinde, lọ sibẹ lati ṣoju ẹ.

Lara awọn ori-ade to tun wa nibẹ ni Olulamokun ti Yakooyo ni ipinlẹ Ọṣun, Onidoo ti Ido (ipinlẹ Ọyọ), ẹni to ṣoju Ọba Lekan Balogun ti i ṣe Olubadan tilẹ Ibadan, atawọn ọba agbegbe Ibarapa. Olu  Igboọra, Ọba Jimọ Ọlajide Titiloye, lo gba gbogbo wọn lalejo.

Leave a Reply