Ipinlẹ Kano lawọn Hausa yii ti waa jale n’Ilọrin, lọwọ NSCDC ba tẹ wọn

Stephen Ajagbe, Ilorin

Afurasi mẹta; Muhammed Zaharadeen, ọmọ ọdun mẹẹẹdọgbọn, Abubakar Sanni, ọmọ ọdun mejidinlogun ati Shamusudeen Abdullahi, ẹni ọdun mẹtalelogun, ti ko sọwọ ajọ NSCDC nipinlẹ Kwara, fẹsun idigunjale.

Awọn mẹtẹẹta ti wọn wa lati abule kan naa, Jermawa, nijọba ibilẹ Bukure, nipinlẹ Kano, lokete boru mọ wọn lọwọ lasiko ti wọn lọọ ji waya ina atawọn pọmbu omi gbe.

Alukoro ileeṣẹ NSCDC, Babawale Zaid Afọlabi, ṣalaye pe ileeṣẹ to n ta oogun oyinbo, Peace Pharmaceutical Company, to wa lẹyin gbọngan nla Stella Ọbasanjọ, lọna Ọffa Garage, niluu Ilọrin, ni wọn lọọ ja lole.

O ni ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lọwọ ba wọn nigba ti wọn ko ẹrọ jẹnẹratọ atawọn nnkan mi-in.

Awọn afurasi naa ti jẹwọ pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun naa. Alukoro ni laipẹ ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply