Florence Babaṣọla
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kegbajare pe ki gbogbo awọn olugbe ilu naa ma ṣe sun asunpara lasiko yii lori ọsẹ ti ajakalẹ arun Koronafairọọsi n ṣe.
Eleyii ko ṣẹyin bi arun naa ṣe tun gbẹmi eeyan mẹtala laarin ọsẹ kan ṣoṣo, yatọ si awọn ti wọn jajabọ ninu arun naa.
Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ilanilọyẹ, Funkẹ Ẹgbẹmọde, fi sita lo ti ṣalaye pe ipele kẹta arun naa wa nipinlẹ Ọṣun bayii, eleyii to si buru jai ju awọn ipele meji akọọkọ lọ.
O ni o n dun ijọba pe awọn araalu ko tiẹ kọbiara si oro itankale arun naa mọ, ṣe ni arun naa si n ṣoro bii agbọn kaakiri bayii.
Ẹgbẹmọde fi kun ọrọ rẹ pe anfaani wa fun ẹni to ba tete mọ pe arun naa ti de agọ ara oun, idi si niyi to fi yẹ ki onikaluuku tete yọnda ara rẹ fun ayẹwo arun Korona lọgan ti wọn ba ti bẹrẹ aisan.
O ni fifi nnkan bo imu, fifọwọ loorekoore pẹlu ọṣẹ, lilo sanitaisa, yiyago fun ipejọpọ ẹlẹni-pupọ ati wiwa ni imọtoto ni gbogbo igba pọn dandan bayii lati le dena itankalẹ arun naa.