Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, ti sọ pe oun o fara mọ ipinnu tawọn gomina iha Guusu ilẹ wa ṣe laipẹ yii pe agbegbe Guusu nikan ni Aarẹ Naijiria ti gbọdọ jade wa, o ni ipinnu to lodi sofin ni, ko si le mulẹ rara.
O ni nnkan torileede yii nilo lọwọ yii ni aarẹ to maa kunju oṣuwọn, ti Naijiria fẹ, to si maa jẹ ẹni ti tewe-tagba fọwọ si, ki i ṣe ọrọ agbegbe ti tọhun ti wa, o niyẹn ko ṣe pataki lasiko yii.
Nibi akanṣe idalẹkọọ ọlọjọ meji kan ti wọn ṣe fun diẹ lara awọn to n gbe iroyin iwa ọdaran ati ọrọ oṣelu jade niluu Abuja ni Bello ti sọrọ ọhun lọjọ Ẹti, Furaidee yii.
Bello, to jẹ olubanisọrọ pataki lọjọ akọkọ idalẹkọọ naa, sọ pe: “Ipo ti Naijiria wa lọwọ yii nilo nnkan to dara ju lọ. Niṣe ni Naijiria da bii ọkọ oju omi kan tabi baaluu kan to jẹ pe atukọ to daa ju lọ, to jafafa ju lọ, lo le mu un gunlẹ sebute ogo.
Aba temi ni pe ka faaye gba oludije to dara ju lọ lati yọju, to maa jẹ ka wa niṣọkan. Ta lo maa ba wa wa ojuutu sawọn ipenija ta a n koju lasiko yii? Ta lo maa tẹsiwaju lori ibi ti Aarẹ Buhari ba baṣẹ de, to maa ṣaleekun awọn nnkan meremere to ti ṣe? Iyẹn lo jẹ ero temi lori ọrọ ayipo ipo aarẹ lati agbegbe kan si omi-in.
To ba jẹ pipaarọ ibi ti aarẹ ti maa wa lo maa yanju iṣoro wa ni, igba ti Aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti gori aleefa fun saa meji niṣoro iha Guusu iba ti yanju kẹ.
Tabi nigba ti Aarẹ Shehu Musa Yar’Adua to ti doloogbe fi wa nipo, o yẹ ki gbogbo iṣoro ilẹ Hausa ti dohun igbagbe, bẹẹ lo si yẹ ko ri lagbegbe Guusu lọhun-un, iyẹn Niger-Delta, nigba ti eeyan wọn wa nipo Aarẹ.
Ta a ba n sọrọ nipa ijọba awa-ara-wa, ijọba to fun-unyan lominira lati yan ẹni to ba wu u ni, kawọn eeyan si yan ẹnikẹni ti wọn ba fẹ. Ọrọ ẹni ti ibo rẹ ba kun ju ni, ibi tawọn eeyan pupọ ba fi si ni, ẹgbẹ oṣelu kan ko gbọdọ gbegi dina ominira tawọn eeyan ni lati yan ẹni to wu wọn lati ibikibi nigbakuugba.
Ọrọ pe agbegbe kan lo maa fa aarẹ kalẹ ko bofin mu, tẹ ẹ ba wo o daadaa. Ko si ninu ofin ẹgbẹ wa, ẹgbẹ oṣelu APC, bẹẹ ni ko sohun to jọ bẹẹ ninu iwe ofin ilẹ wa, tọdun 1999 ta a n lo lọwọlọwọ.
Bo ba si waa jẹ pe a fẹẹ maa pinnu agbegbe ti aarẹ kan yoo ti wa funra wa ni, ẹ jẹ ka tun gbogbo ọrọ naa yẹwo daadaa lati ọdun 1960 ti a ti gba ominira, ki i ṣe ọdun 1999 la ti maa mu un.”
Bayii ni Gomina Yahaya Bello ṣe sọrọ rẹ.