Wọn yinbọn pa igbakeji MC Oluọmọ nibi ipolongo ibo APC l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 Niṣe lọrọ di bo-o-lọ-o-yago nigba ti iro ibọn ṣadeede dun, to si ṣeku pa igbakeji alaga ẹgbẹ onimọto NURTW, ẹka ti Eko, Ọgbẹni Kayọde Samuel, ti inagijẹ rẹ n jẹ Epo Kinkin, nibi eto kampeeni ẹgbẹ APC kan ti wọn ṣe lagbegbe Agboju, nijọba ibilẹ Onidagbasoke Oriade, l’Ekoo.

Ba a ṣe gbọ, owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, niṣẹlẹ naa waye, ọkan lara awọn ero to pejọ sabẹ kanopi ti wọn ti n polongo ibo ni wọn lo yinbọn fun oloogbe naa.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ sọ pe ọkan lara awọn to fẹẹ dije fun ipo alaga kansu Oriade lagbegbe Agboju ni Epo kinkin n ṣatilẹyin fun lọwọ nibi ipolongo ọhun ti wọn fi yinbọn pa a.

O ni niṣe lọrọ di pẹẹ-n-tuka gbara tawọn eeyan gburoo ibọn, ti oloogbe naa si kigbe oro laarin awọn ero to wa nita, nibi ti wọn ti yinbọn fun.

O ni nigba tawọn fi maa mọ ohun to n ṣẹlẹ, Epo Kinkin ti ṣubu lulẹ sinu agbara ẹjẹ, o si ti ku.

Lara awọn to wa nibi ipolongo naa nigba tiṣẹlẹ ọhun waye ni alaga kansu Amuwo-Ọdọfin, Ọgbẹni Valentine Buraimọh, atawọn oloṣelu ẹgbẹ APC lagbegbe ọhun.

Ọgbẹni Jimọh Buhari to jẹ agbẹnusọ fun Alaga ẹgbẹ awọn onimọto Eko, Musiliu Akinsanya, tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin.

O ni nnkan tawọn gbọ ni pe oloogbe naa n gbiyanju lati daabo bo oloṣelu ẹgbẹ rẹ kan, Ọgbẹni Wale Oke, nibi ipolongo naa lọwọ ni, pẹlu bawọn janduku kan ṣe fẹẹ kọ lu u, ṣugbọn niṣe ni wọn papa yinbọn fun un, to si ku loju-ẹsẹ.

O lawọn ti lọọ fọrọ yii to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

Ko ti i sẹni to mọ ohun to wa nidii iṣẹlẹ yii, bẹẹ ni ko ṣee ṣe lati gbọrọ lẹnu Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko lori iṣẹlẹ yii, tori ko gbe aago rẹ, bẹẹ ni ko ti i fesi si atẹjiṣẹ ta a fi ṣọwọ sori ikanni ayelujara rẹ, ti a fi ko iroyin yii jọ.

Leave a Reply