Ipo ti eto aabo ipinlẹ Kwara wa bayii ti n kọja afarada – Sẹnetọ Rafiu

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Guusu ipinlẹ Kwara tẹlẹ, Rafiu Adebayọ Ibrahim, ti kọminu lori ipo ti eto aabo ipinlẹ Kwara wa bayii, o ni afi ki ijọba tete wa ọna abayọ.

Ninu atẹjade kan ti Adebayọ fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ niluu Ilọrin, lo ti sọ pe nibi ti eto aabo ipinlẹ Kwara de duro bayii, o ti n kọja afarada. Ọkunrin naa ni ṣe ti awọn Fulani darandaran ti wọn n ṣe akọlu si awọn agbẹ la fẹẹ sọ ni, abi ti awọn ajinigbe, oloko o le roko, olodo o le rodo, bi wọn ṣe ni ji ara ile gbe ni wọn pa agbẹ lọna oko.

Adebayọ ni oun to si fa a ni pe gbogbo ẹnubode to wọ ipinlẹ Kwara lo ṣi silẹ gbayau, ti awọn Fulani darandaran si n ya wọ ipinlẹ naa kẹti kẹti, o ni ọrọ naa gba amojuto.

Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o ni ki ijọba ipinlẹ Kwara tete wa wọrọkọ fi sada lori ọrọ eto aabo ti ko rajaja, tori pe ojuse akọkọ ti ijọba gbọdọ mu ni ọkunkundun ni eto aabo, ki ijọba fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn ọba alaye ati gbogbo lẹka lẹka eto aabo, ki awọn olugbe ipinlẹ Kwara le maa sun oorun asun diju, tori pe aisi eto aabo n ṣe akoba fun eto ọrọ aje ipinlẹ naa.

Leave a Reply