Ireti wa fun orileede wa lati goke agba ti a ba le gbogun ti awọn nnkan to n fa iyapa laarin wa – Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, ti ke si gbogbo awọn ọmọ orileede lati jawọ ninu oniruuru ẹtanu ati awọn itara-odi to n pagi dina iṣọkan, alaafia ati itẹsiwaju Naijiria.
Ireti ṣi wa fun orileede yii lati dide ninu erọfọ ifidi-rẹmi ati awọn aṣiṣe ọdun pipẹ

Oyetọla ṣalaye pe, “Ireti ṣi wa fun orileede yii lati dide ninu erọfọ ifidi-rẹmi ati awọn aṣiṣe ọdun pipẹ, ko si goke agba niwọn igba ti gbogbo wa ba le gbagbe ẹtanu ati itara-odi ọlọjọ pipẹ ti ko jẹ ka ni iṣọkan, alaafia ati itẹsiwaju.

“A gbọdọ ṣe ara wa lọkan fun atunṣe ilẹ wa. Ka gbaju mọ awọn nnkan to so wa papọ lati le kọ orileede ati ijọba tiwa-n-tiwa ti yoo mu ki aye dun un gbe fun gbogbo wa”.

Oludanilẹkọọ nibi eto naa, Ọjọgbọn Ṣọla Akinrinade, sọ pe orileede yii gbọdọ wa ọna lati mu adinku ba owo to wa nidii oṣelu, nitori o n ṣe ipalara nla fun idagbasoke ilẹ wa.

Akinrinade ni iwa jẹgudujẹra ti gbilẹ ju ni Naijiria, oniruuru awọn iwa ipa naa ko si gbẹyin, eleyii si n fi orileede wa han gẹgẹ bii awujọ to n ṣaisan.

O ni, pẹlu iye awọn aṣofin ti a ni kaakiri, kikuna lati mu atunto ba ilana iṣẹ ijọba, iwa jẹgudujẹra to wa kaakiri ẹka iṣejọba, iwa ibajẹ to wa ni ileeṣẹ ti wọn ti n pọn epo rọbi ati bẹẹ bẹẹ lọ, o fihan pe iṣẹ nla ṣi wa niwaju lati ṣe.

Akinrinade fi kun ọrọ rẹ pe ko gbọdọ jẹ awọn aṣofin nikan ni wọn a maa sọ iṣẹ akanṣe ti wọn ba fẹẹ ṣe fun awọn eeyan wọn, awọn araalu naa gbọdọ le sọ nnkan ti wọn ba fẹ, eleyii ni ko ni i jẹ ki awọn aṣofin maa gapa kaakiri bii ẹni pe owo apo wọn ni wọn fi ṣe e.

Bakan naa, Agbẹjoro agba, Adegboyega Awomọlọ, sọ pe orileede yii ni idi to pọ lati maa ṣeranti ọjọ ijọba tiwa-n-tiwa. O ni bi nnkan ko kan tiẹ ti i duro deede tan, sibẹ, oniruuru idagbasoke to wa kaakiri ẹkajẹka jẹ ọkan lara awọn ere ijọba tiwa-n-tiwa.

Ninu ọrọ tirẹ, Kọmiṣanna fun ọrọ ibaṣepọ agbegbe ati iṣẹ akanṣe l’Ọṣun, Ẹnjinnia Lekan Badmus, sọ pe bi ijọba apapọ ṣe sọ orukọ MKO Abiọla di manigbagbe jẹ igbesẹ to tọna pupọ, bẹẹ nijọba to wa nipinlẹ Ọṣun lọwọlọwọ n ṣafihan gbogbo nnkan ti Abiọla nigbagbọ ninu rẹ nigba to wa laye.

O ni Gomina Oyetọla ki i da ohunkohun ṣe, yoo beere lọwọ awọn araalu, ohun ti awọn araalu ba si sọ pe awọn fẹ nijọba n ṣe. Badmus ṣapejuwe Oyetọla gẹgẹ bii olotitọ, alaaanu ati ọlọpọlọ pipe ẹda.

Leave a Reply