Irin reluwee lawọn mẹfa yii n ji tu ti wọn fi mu wọn n’Ibogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ Sannde tọpọ eeyan n sinmi nile, awọn ọkunrin mẹfa yii ko sinmi. Oju irin reluwee to gba Ọtẹyi kọja, n’Ibogun, nijọba ibilẹ Ifọ, nipinlẹ Ogun, ni wọn ti n ji irin to gba oju ọna naa tu, kọwọ palaba wọn too segi.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun to fi to ALAROYE leti ṣalaye pe Sannde, ọgbọnjọ, oṣu karun-un, ni awọn ọkunrin naa, Taiwo Ismaila, Ẹgbẹkunle Abiọdun, Abdullah Sanni, Nuru Ibrahim, Wasiu Awẹda ati Babatunde Sikiru n ba oju irin naa jẹ nitori ati ji awọn irin kan tu nibẹ.

Ohun ti wọn n ṣe lọwọ ree ti olobo fi ta DPO teṣan Ibogun, CSP Samuel Ọladele, bi wọn ṣe lọ sibẹ niyẹn, ti wọn si ba awọn gende mẹfa naa nibi ti wọn ti n fa irin yọ loju ọna reluwee ọhun, kia ni wọn fọwọ ofin mu wọn, ti wọn ko wọn da si mọto.

Awọn irin ti wọn ti tu loju ọna reluwee naa pẹlu mọto ti wọn n ko o si lawọn ọlọpaa sọ pe awọn ri gba lọwọ wọn.

Irin mẹtadinlọgbọn, okun ti wọn fi n fa omi tabi afẹfẹ (hose), agolo gaasi (cylinder) mẹfa to gun daadaa ati kekere mẹta ni wọn ba lọwọ wọn. Mọto tirela ti wọn waa fi ko o ni nọmba ẹ jẹ SMK 61 XY.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun ti ni ki wọn ko awọn mẹfẹẹfa yii lọ sẹka to n gbọ iwa bii eyi, nibi ti wọn yoo ti ṣewe kootu fun wọn.

Leave a Reply