Irọ to jinna si ootọ ni pe mo n ṣatilẹyin fun Tinubu- Pasitọ Tunde Bakare

Monisọla Saka

Olori ijọ Citadel Global Community Church, ti gbogbo eeyan mọ si Latter Rain Assembly tẹlẹ, nipinlẹ Eko, Pasitọ Tunde Bakare, ti jade sita lati wẹ ara ẹ mọ pe ahesọ ọrọ ni pe oun fontẹ lu oludije dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, gẹgẹ bii aarẹ ninu ibo to n bọ lọna lọdun 2023, tabi pe oun ṣaltilẹyin fun ki Musulumi jẹ aarẹ ati igbakeji rẹ. Bakare sọrọ yii ninu atẹjade to fi lede pe irọ pata gbaa ni pe oun n ṣiṣẹ ta ko akojọpọ ajọ ẹgbẹ Onigbagbọ (CAN), lorilẹ-ede yii lori ipinnu Tinubu lati fi Kashim Shettima to jẹ Musulumi bii tiẹ ṣe igbakeji ẹ ninu ibo ọdun to n bọ. Ninu ọrọ ti ojiṣẹ Ọlọrun yii ṣẹṣẹ gbe sori ẹrọ ayelujara ‘Facebook’ rẹ, o ṣapejuwe ọrọ ti wọn lo sọ ọhun bii irọ pọnnbele. Bakare ni, “Wọn ti pakiyesi mi si ọrọ kan to n ja ran-in ran-in nilẹ, ọrọ runrun kan tawọn ọbayejẹ oniroyin ori ẹrọ ayelujara sọ ta ko mi. Ninu ọrọ yii ni wọn ti sọ pe mo ni awọn PDP ni wọn wa nidii gbogbo ifẹhonu han ti CAN n ṣe lati le ti eeyan ti ko kun oju oṣuwọn mọ awọn APC lọrun, ki wọn fa a kalẹ gẹgẹ bii oudije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ wọn. “Bakan naa ni wọn tun sọ pe mo lawọn CAN fẹẹ ti eeyan ti ko kun oju oṣuwọn mọ APC lọrun fun ipo aarẹ. Awọn olubi akọroyin yii tun ni emi sọ pe eeyan ire to n huwa bii Jesu Kristi lawọn Kirisitẹni, nigba tawọn CAN jẹ oloṣelu ti wọn n huwa bii awọn PDP. “Afi bii pe irọ yii o ti i to, wọn ni mo sọ pe eeyan mi ni Tinubu, pe tiẹ ni mo si n ṣe. Ni Tinubu ti mo kede fun gbogbo aye ri nibi ipade apero pe mi o le fipo silẹ fun. Oun lo ti waa sare di eeyan mi bayii! “Mo n fi akoko yii sọ fawọn eeyan pe irọ nla banta banta gbaa ni gbogbo awọn ọrọ yii, nitori ko si ibi ti mo ti ṣe ifọrọwerọ pẹlu ẹnikẹni, bẹẹ ni mi o waasu awọn irọ yii níbikíbi. Ta a ba waa ri ẹnikẹni to loun ni fidio abi rẹkọọdu ibi ti mo ti sọ awọn ọrọ yii, ko gbe e saye fun gbogbo wa lati ri. “Atunluuṣe ti ko ni i figba kankan fa ipinya laarin awọn eeyan orilẹ-ede yii nipasẹ ọrọ ẹsin tabi oṣelu ni mi. Mo wa n fi akoko yii rọ awọn eeyan lati ma ṣe ka awọn ọrọ naa kun. Emi kọ ni mo sọ awọn ọrọ yẹn. Lara awọn ọgbọn ete buruku tawọn olori buruku ti wọn n fẹ ibuwọlu ijọba n fi gbogbo ọna wa ree. Tawọn eeyan ibi yii o ba si jawọ ninu iwa aburu ọwọ wọn yii, wọn aa pada foju bale-ẹjọ ni.

Leave a Reply