Iru Aarẹ ti ko gba gbẹrẹ bii Buhari yii lo daa fun Naijiria – Fẹmi Adeṣina

Faith Adebọla

Oludamọran pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori eto iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, ti sọ pe niṣe lo yẹ kawọn ọmọ Naijiria maa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe Aarẹ to mọṣẹ rẹ niṣẹ, ti ko gboju bọrọ, ti ko si raaye rẹdẹrẹdẹ lo n tukọ orileede naa lasiko yii.

O ni eyi lo mu ko ṣee ṣe fun Buhari lati mọ iru ibawi to tọ si awọn to n daluru kaakiri orileede yii.

Ninu apilẹkọ kan to fi lede lọjọ Aje, Mọnde yii, lo ti sọ eyi di mimọ. O ni ọrọ ti Buhari sọ laipẹ yii pe oun maa da sẹria fawọn to n dana ijangbọn lorileede yii bii ti igba ogun abẹle to kọja ko tumọ si pe ọga oun jẹ arogun-yọ, ṣugbọn ohun ti Buhari n sọ ni pe oun gẹgẹ bii olori ko ni i gba kawọn kan sọ eto aabo to mẹhẹ yii di awawi lati maa paayan bii ẹran, ki wọn si maa ba dukia jẹ kaakiri.

Fẹmi ni: “Ọwọ to le koko lorileede wa nilo lasiko yii, adapọ iṣakoso bii ologun ati Aarẹ. Loootọ la wa labẹ iṣakoso oloṣelu, ṣugbọn iyẹn ko tumọ si pe kawọn eeyan taku sidii iwa ailofin.

Ti ẹnikẹni ba tasẹ agẹrẹ nibikibi, ani nibikibi lorileede yii, a gbọdọ fun wọn lẹgba ki wọn le gbọran ni. A o le gba kawọn kan dori ilu kodo nitori pe inu n bi wọn, ibinu ọhun si pọ.

“Ki lẹyin eeyan n fẹ gan-an? Nigba ti Buhari parọwa pe kawọn eeyan bomi suuru mu, ki wọn ma gbomi wahala kana, ẹ ni niṣe lo n sọrọ bii oniwaasu, nisinyii to si tun sọrọ bii ologun, ẹ tun ni idunkooko mọ ni ni.”

Fẹmi pari ọrọ rẹ pe Aarẹ Buhari maa ṣe gbogbo ohun to gba lati ri i pe oun dirọ mọ ofin ilẹ wa, ko si ni i gba ki wọn doju ijọba rẹ de.

Leave a Reply