Monisọla Saka
Kayeefi ni iku awọn mẹsan-an kan ti wọn jẹ mọlẹbi kan naa niluu Nagazi, nijọba ibilẹ Adavi, nipinlẹ Kogi, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa yii, jẹ fawọn eeyan. Awọn ọmọ iya kan naa marun-un pẹlu awọn mẹrin kan niṣẹlẹ ibanujẹ naa ṣẹlẹ si, to si ṣe bẹẹ mu ẹmi wọn lọ lai ro tẹlẹ lẹyin ti wọn jẹ amala tan.
Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ni wọn ni awọn marun-un kọkọ fo ṣanlẹ ti wọn gbẹmi-in mi. Wọn o tilẹ roju ṣe ọfọ tabi idaro awọn to ku yii ti wọn fi gbe awọn mẹrin yooku to n pọkaka iku digbadigba lọ sile iwosan kan ti wọn o darukọ ẹ, lati du ẹmi wọn. Ṣugbọn o ba ni lọkan jẹ pe ọsibitu ti wọn gbe awọn mẹrin yii lọ lawọn naa ti pada dagbere faye.
Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ pe majele lo pa wọn. Boya majele wa ninu ounjẹ tabi omi ti gbogbo wọn mu.