Ibeere yii lawọn eeyan n beere lori atẹ ayelujara pẹlu iṣẹlẹ a-gbọ-gbari-mu kan to waye lọjọ Abamẹta, Satide, wọn lọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan, Nonso Eze, loun ati ololufẹ ẹ n ṣe gbolohun asọ, bẹẹ lo ba fibinu ti obirin naa, Ifeoma, danu, lori ile alaja marun-un ti wọn n gbe, bẹẹ lobinrin naa ṣe sori mọlẹ, to si ku fin-in fin-in loju ẹsẹ.
Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, (NAN) ṣalaye pe Ojule kẹfa, Opopona Orakwe, ni Awada Obosi, nijọba ibilẹ Ariwa Idemili, nipinlẹ Anambra, niṣẹlẹ naa ti waye ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ Abamẹta.
Awọn aladuugbo kan ti wọn n gbọ ariwo gbolohun asọ to ti ṣẹlẹ ṣaaju laarin awọn ololufẹ meji yii lo sare sibi iṣẹlẹ naa, wọn tiẹ sare gbe oloogbe naa de ileewosan Bex Hospital, to wa l’Onitsha, ibẹ ni dokita ti sọ fun wọn pe oku ni wọn gbe wa.
Awọn aladuugbo naa ko jẹ ki Nonso ribi sa lọ, wọn tiẹ loun naa fẹẹ bẹ silẹ latori ile ọhun nigba to ri itu toun fibinu pa, ṣugbọn wọn ra a mu, wọn din dundu iya fun un, ki wọn too wọ ọ lọ sagọọ ọlọpaa to wa lagbegbe Awada-Obosi.
Ṣa, bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa ṣe sọ, awọn ọlọpaa ti gbe oku obinrin naa si mọṣuari ileewosan ijọba fun ayẹwo, Nonso naa si ti wa lakata wọn.