Tirela Dangote tun tẹ ọpọ eeyan pa l’Akungba Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn agbalagba bii mẹjọ lo tun pade iku ojiji ninu ijamba ọkọ mi-in to waye niluu Akungba Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide.

Ni ibamu pẹlu alaye ti ọkan ninu awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ ṣe fun akọroyin ALAROYE, o ni tirela to jẹ ti ileesẹ Dangote naa lo padanu ijanu rẹ lojiji lasiko to n sọkalẹ ori oke nla kan, to si ṣe bẹẹ lọọ kọ lu ọgọọrọ awọn eeyan to wa lẹnu abawọle Fasiti Adekunle Ajasin, to wa niluu Akungba.

O kere tan, awọn eeyan bii mẹjọ lo ni wọn ku loju ẹsẹ, nigba tawọn mi-in ọ̀i wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun lasiko to n ba wa sọrọ naa.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun wa lori foonu, o ni oku eeyan mẹjọ lawọn ẹsọ oju popo si ri fa jade labẹ tirela naa.

O ni awọn ẹsọ alaabo ọ̀i n ṣakitiyan lọwọ lati mọ boya awọn eeyan ọ̀i ku ti wọn ha sabẹ ọkọ ajagbe ọhun.

Leave a Reply