Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni talẹ-talẹ kan (land agent), Alaaji Taiye Hussein Abubakar, ẹni ọdun mẹtalelọgọta, ku lojiji, lẹyin ti wọn fi i ṣahaamọ ọgba ẹwọn Òke-Kúrá, niluu Ilọrin, lati bii oṣu mẹrin ṣẹyin.
ALAROYE gbọ pe gbajumọ ninu ka ba ni ra ilẹ tabi ta ilẹ ni oloogbe yii, sugbọn ilẹ kan to ta fun onibaara rẹ lo di wahala to di dero ile-ẹjọ.
Ọkan lara awọn mọlẹbi oloogbe to ba awọn oniroyin ṣọrọ bu ẹnu atẹlu ile-ẹjọ ati alaṣẹ ọgba ẹwọn gẹgẹ bo ṣe fẹsun kan wọn pe aọn ni wọn pa Oloogbe Hussein.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Hussein lọwọ ninu ilẹ tita kan, to si di ọrọ ile-ẹjọ. Kootu gba beeli rẹ, ṣugbọn ko raaye fara han ni kootu lọjọ ti wọn sun igbẹjọ mi-in si latari pe ara rẹ ko ya. Awọn ọlọpaa tun lọọ mu un, ti wọn si fi i ṣahaamọ ọgba ẹwọn latigba naa lọhun-un, ti wọn si pa a ti si ahamọ lati bii oṣu mẹrin si marun-un ṣẹyin. Eyi to si yẹ ki wọn fun un lore-ọfẹ lẹẹkan si i. Bawo lo ṣe fẹẹ rowo ti yoo san pada fun ẹni to ni in ti wọn ko ba fi i silẹ lahaamọ ọgba ẹwọn? A lọọ bẹ adajọ ko gba beeli rẹ pẹlu awọn oniduuro, ṣugbọn gbogbo igbiyanju wa lo ja si pabo.
“Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, la gbọ pe wọn sare gbe e lọ si ileewosan. Awọn kan sọ pe wọn o ti i gbe e de ọsibitu to fi ku lọna, awọn miiran sọ pe lasiko to n gba itọju lọwọ lo ku. Ilera rẹ ko pe tẹlẹ ko too ku, adajọ si mọ si eyi”
Alukoro ileeṣẹ ọgba ẹwọn ni Kwara, Phillip Adegbulugbe, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun ALAROYE, o ni oloogbe ọhun ku sileewosan latari aisan kidinrin to n yọ ọ lẹnu.
“Ileewosan Jẹnẹra ilu Ilọrin ni wọn gbe e lọ, ibẹ naa lo si ku si. Mo ri faiili rẹ to ṣalaye iru aisan to n ṣe e. Alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni wọn gbe e lọ sileewosan, to si ku ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii. Ko ku si inu ọgba ẹwọn gẹgẹ bi awọn kan ṣe n gbe e kiri. Emi naa ṣẹṣẹ dari de lati ileewosan ni”