Faith Adebọla, Eko
Ariwo, ‘ikunlẹ abiyamọ o’ lo gba ẹnu awọn eeyan ti wọn n wo oku awọn majeṣin mẹjọ ti wọn ko jade ninu ọkọ ayọkẹlẹ kan ni Ojule kejidinlogun, Opopona Adelayọ, nibudokọ Jah Michael, to wa lagbegbe Badagry, nijọba ibilẹ Ọlọrunda, nipinlẹ Eko, lọjọ Aiku, Sannde yii. Wọn ni niṣe lawọn ọmọ naa n ṣere ninu ọkọ ọhun, lasiko naa ni ilẹkun pa de mọ wọn lojiji, wọn ko si ri i ṣi titi ti ooru fi mu wọn pa sinu ọkọ naa.
Atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko fi ṣọwọ sori atẹ ayelujara ALAROYE nipa iṣẹlẹ naa, CSP Adekunle Ajiṣebutu sọ pe ọkọ ayọkẹlẹ naa ko ṣẹṣẹ debẹ, o ti wa nibẹ tipẹ, Saliat Kazeem ni wọn lo ni ọkọ ọhun.
Ko sẹni to le sọ pato asiko tawọn ọmọde ti wọn lọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹwaa si marun-un yii ṣere dedii ọkọ ọhun, ti wọn si ṣilẹkun ọkọ, ti wọn pa ilẹkun ọhun de mọ ara wọn nibẹ.
Ẹnikan to n kọja lọ lo taju kan an ri i pe awọn ọmọ naa ti sun, lo ba pe akiyesi awọn to wa laduugbo si i, igba naa lawọn eeyan too fura pe ina nla ti jo obi awọn ọmọleewe yii.
A gbọ pe binrin to ni mọto naa tun jẹ lanlọọdu ile kan nibẹ, ọkan ninu awọn ọmọọmọ rẹ naa wa ninu awọn ti wọn wa ninu ọkọ ọhun.
A gbọ pe nigba ti wọn n gbe ọkan ninu awọn ọmọ naa ki ko ku loju-ẹsẹ lọ sọsibitu ni oun naa pada jade laye.
Ṣa, CP Hakeem Odumosu ti paṣẹ pe kawọn oniṣegun ṣayẹwo si oku wọn lati mọ pato ohun to pa wọn, ati bi iku abaadi ọhun ṣe jẹ, o si ti ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ iṣẹ iwadii to lọọrin lori ọrọ yii.
Awọn ọlọpaa Morogbo, lagbegbe Badagry lo waa ko awọn oku ọmọ naa .
Ọpọ awọn aladuugbo naa lo n sọ pe ooru lo ṣee ṣe ko mu awọn ọmọ naa pa sinu ọkọ ọhun, bẹẹ lawọn kan n sọ pe ejo ọrọ yii lọwọ ninu, boya wọn fa atẹgun onimajele tabi ki ewu mi-in ti wu wọn ninu ọkọ naa.
Mọṣuary ọsibiju Jẹnẹra Badagry ni oku awọn mẹjẹẹjọ wa bayii.