Iru ki waa leleyii, ọmọkunrin yii si para ẹ niwaju iya ẹ ni Surulere

Faith Adebọla

 Bi ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Aboh Ogbeche, ṣe jokoo siwaju mama ẹ ni palọ wọn, to si n da majele jẹ bii ẹni mu miniraasi titi to fi ku jẹ iyalẹnu fun ọpọ awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ naa.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, niṣẹlẹ buruku ọhun waye ninu ile ti Aboh n gbe pẹlu mama atawọn mọlẹbi ẹ, lagbegbe Lawanson, ni Surulere, nipinlẹ Eko, bo tilẹ jẹ pe ọmọ bibi ipinlẹ Cross River ni.

Ko ti i sẹni to mọ pato ohun tọmọkunrin yii ro to fi ṣepinnu buruku yii, ṣugbọn ọna to gba gbẹmin ara ẹ naa kọọyan lominu gidi, ọpọ lo si n ṣe kayeefi nipa iku rẹ ọhun tori ko fu ẹnikẹni lara rara.

Ohun ta a gbọ ni pe ni nnkan bii aago mẹta aabọ irọlẹ ọjọ naa loloogbe yii jokoo siwaju mama rẹ pẹlu ife kan to gbe sori tabili to wa ni palọ wọn, loun ati mama naa ba n takurọsọ, wọn jọ n jiroro.

Aṣe kẹmika bliiṣi (bleach) tawọn eeyan fi n ṣi idọti lara aṣọ lo wa ninu kọọbu to gbe dani, bi wọn ṣe n sọrọ naa lo n da kinni ọhun sọfun, to n dọgbọn rẹrin-in, debii pe mama rẹ gan-an ko fura pe majele lọmọ toun n ba sọrọ n da jẹ.

Ori ijokoo naa ni wọn ṣi wa ti kẹmika naa jiṣẹ toloogbe ọhun ran an, ni Aboh ba bẹrẹ si i lọnu mọlẹ, o n pofolo, niya ba ke sawọn aladuugbo pe ki wọn gba oun, kia si lawọn to wa nitosi dide iranlọwọ, ti wọn gbe e digbadigba lọọ sileewosan ti wọn n pe ni Aisat Hospital, to wa ni Idi-Arara, ibẹ la gbọ pe oloogbe naa dakẹ si.

Awọn aladuugbo ti wọn waa ṣaajo naa ni wọn kiyesi ralẹralẹ nnkan ti Aboh n gbe mu ninu kọọpu, ni wọn ba ri i pe majele ni, nigba ti wọn si tun wo yara rẹ, wọn ba awọn lailọọnu saṣẹẹti bliiṣi to ja silẹ nibẹ pẹlu.

Ki lo waa le mu ki ọmọkunrin yii para ẹ? Abi wọn sa si i ni? Ṣe o ni aawọ pẹlu ẹnikan ni? Oriṣii ibeere bawọnyi lawọn eeyan n gbe pooyi ẹnu ninu ọrọ ti wọn kọ nipa oloogbe naa sori atẹ fesibuuku rẹ, tori awọn to mọ ọn sọ pe eeyan jẹẹjẹ ni, ọmọluabi si ni pẹlu.

Ṣa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana, lawọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii, o loootọ lo waye, awọn si ti gbe oku naa sọsibitu ti wọn ti maa ṣayẹwo si i.

Elkana ni ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to n ri si iwa ọdaran abẹle ti tẹwọ gbaṣẹ iwadii iṣẹlẹ ibanujẹ naa.

 

Leave a Reply