Ismaila fẹẹ fi aburo rẹ ṣowo ni Kwara, lo ba du u bii ẹran 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Ismail Saliu, fẹsun pe o lẹdi apo pọ pẹlu baba oloogun owo kan, to si du aburo rẹ, Azeez Saliu ẹni ọdun mẹrinla bii ẹran niluu Kosubosu, ijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, latari pe o fẹẹ fi ṣẹṣo owo.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, buwọ lu to tẹ ALAROYE, lọwọ niluu Ilọrin, lo ti sọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni iṣẹlẹ naa waye ni ilu Kosubosu, nijọba ibilẹ Baruten. Nigba ti awọn ara agbegbe ọhun lọọ fi iroyin iṣẹlẹ buruku naa to ajọ ṣifu difẹnsi leti ni ọfiisi wọn to wa niluu ọhun ni wọn lọọ mu gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ ọhun. Awọn ti wọn mu ọhun ni: Ahmed Nkwe, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, lsmaila Saliu, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ati Saliu Ahmed, ẹni ọgbọn ọdun. Afọlabi tẹsiwaju pe inu oko lo tan aburo rẹ lọ to fi pa a, ti ọwọ si pada tẹ ẹ lẹyin ti wọn ṣiṣẹ aburu naa tan ti wọn n pada bọ lati oko.

Ismail to jẹ ẹgbọn oloogbe jẹwọ pe loootọ loun ṣeku pa aburo oun pẹlu iranlọwọ ẹni to fẹẹ ba wọn ṣe oogun owo ati ẹni kan to sikẹta wọn.

Afọlabi ni awọn ti fi iṣẹlẹ naa to adari agba ajọ naa nipinlẹ Kwara, lskil Ayinla Makinde, leti, o si ti paṣẹ ki wọn fa wọn le ọlọpaa lọwọ fun itẹsiwaju iwadii.

 

Leave a Reply