Itajẹsilẹ to n ṣẹlẹ lojoojumọ le fa ibinu Ọlọrun fun Naijiria-Ẹlẹbuibọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Araba Awo ti ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, ti ke sijọba apapọ orileede yii lati tete wa nnkan ṣe si ọrọ itajẹsilẹ to n waye lojoojumọ, ki Ọlọrun too rọjo ibinu rẹ silẹ.

Ẹlẹbuibọn sọrọ yii lasiko ajọdun ẹgbẹ awọn ajẹ ati emere nipinlẹ Ọṣun, eleyii to waye ni Araba Castle, niluu Oṣogbo, lopin ọsẹ to kọja. Baba yii sọ pe ewu nla ni itajẹsilẹ ni, ikorira si ni loju Ọlọrun nitori gbogbo ẹmi lo ṣe pataki.

Araba Awo ṣalaye pe ipaniyan niha Ariwa orileede yii ati ipaniṣowo niha Guusu gbọdọ dẹkun nitori inu Ọlọrun ko dun si i rara, ko si si ẹni to lori lati gba a ti ẹsan awọn iwa naa ba de.

Bakan naa ni Ẹlẹbuibọn gba awọn olori ẹsin gbogbo nimọran lati ni oye kikun nipa ẹsin ti wọn gbe lọwọ, ki wọn si jawọ ninu gbigbe ẹsin ayalo ga ju ẹsin adayeba wa lọ. O ni ki wọn jẹ ẹni-pipe, ti ko labawọn ninu ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe.

O ni ọpọlọpọ n ṣiṣẹ bii erin, ṣugbọn wọn n jẹ ijẹ ẹliri nitori pe wọn kuna lati mojuto ẹgbẹ ti wọn ni, o ni ko si ẹni to wa laye yii ti ko ni ẹgbẹ, o si pọn dandan lati mọ eewọ tabi nnkan ti ẹgbẹ eeyan fẹran, igba yẹn ni aluyọ yoo wa kiakia.

Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn ajẹ ati emere naa gbọdọ maa gbe igbe-aye ododo, ki wọn wa lalaafia pẹlu gbogbo eniyan, ki wọn si maa rin nibaamu pẹlu ilana ẹsin abalaye, nigba yẹn lawọn eeyan yoo nifẹẹ lati darapọ mọ wọn.

Ninu ọrọ tirẹ, alakooso ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun, Oloye (Iyaafin) Oyelọla Ẹlẹbuibọn, sọ pe awọn ṣe ajọdun naa ki gbogbo aye le mọ pe ẹgbẹ awọn ki i ṣe ẹgbẹ buburu gẹgẹ bi awọn kan ṣe maa n sọ.

Oyelọla ṣalaye pe ẹgbẹ alaafia, ẹgbẹ imọlẹ, ẹgbẹ to n mu idagbasoke ba ẹni to ba lo o daadaa ni ẹgbẹ naa, awọn adari ẹsin ni wọn kan n ba ẹgbẹ awọn lorukọ jẹ.

O waa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati ma ṣe gbọ tẹlẹgan rara, ki wọn ma ṣe feti si ariwo ọja, ki wọn gbe otitọ ati ootọ-inu wọ bii ẹwu, ki wọn si maa fi ẹgbẹ naa yangan nibikibi ti wọn ba de.

@@@@@@@

One thought on “Itajẹsilẹ to n ṣẹlẹ lojoojumọ le fa ibinu Ọlọrun fun Naijiria-Ẹlẹbuibọn

Leave a Reply