Faith Adebọla
Ijọba apapọ ilẹ wa ti kede lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji, oṣu Karun-un, ati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Keji, ọdun yii, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.
Ọlude naa waye latari ayẹyẹ ayajọ awọn oṣiṣẹ to bọ si ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun yii, ati ayẹyẹ ọdun itunu aawẹ to bọ sọjọ Aiku, Sannde, kan naa.
Atẹjade kan lati ọfiisi Minisita fọrọ abẹlẹ, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, eyi ti Akọwe agba nileeṣẹ naa, Shuaib Belgore, buwọ lu lorukọ rẹ fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe ijọba fẹ kawọn oṣiṣẹ atawọn ẹlẹsin Musulumi fi ọlude naa gbadun ara wọn, ki wọn si fi gbadura fun orileede wa.
Apa kan atẹjade naa ka pe: “Ijọba gboṣuba fawọn oṣiṣẹ fun iṣẹ takun-takun ti wọn n ṣe, iwa akikanju, ifarajin, iṣọkan ati iṣapa wọn latẹyinwa, eyi to mu ki orileede wa maa goke agba, ti Naijiria fi di orileede ti wọn n wari fun lagbaaye. Awọn oṣiṣẹ lo fihan pe a wa laaye, tori ẹni to n ṣiṣẹ lo wa laaye, ẹni to ba ti ku ko le ṣiṣẹ.
“Mo tun ba awọn ẹlẹsin Musulumi yọ jake-jado orileede wa fun ti ọdun itunu aawẹ yii. Mo rọ wọn lati ṣamulo ẹkọ to wa ninu ohun ti aawẹ Ramaddan duro fun, bii fifi ifẹ han si ọmọlakeji, ṣiṣaanu awọn aladuugbo wa, nini ifarada, alaafia, ifara-ẹni-rubọ, gẹgẹ bi Anọbi Mohammad ṣe fapẹẹrẹ lelẹ.”