Faith Adebọla
Bi gbajugbaja oṣere onitiata to wa lahaamọ awọn ọlọpaa bayii, Ọlanrewaju James Omiyinka tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa ba n dunnu lapa kan latari bi wọn ṣe lawọn ọlọpaa ni awọn maa gba beeli rẹ, ko jọ pe idunnu naa maa dalẹ, tori ijọba apapọ ti sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan an, wọn ni fọpawọn lẹwọn ẹ maa jẹ nigba tile-ẹjọ ba maa gbe idajọ kalẹ lori ọrọ ẹ.
Alaga NIDCOM, iyẹn ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria to wa lẹyin odi (Nigerians in Diaspora Commission), Abilekọ Abikẹ Dabiri-Erewa lo ta sọrọ yii lori ikanni abẹyẹfo (tuita) rẹ lori atẹ ayelujara, o sọ pe oun ti gbọ nipa ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa, iwa naa si riiyan lara gidi.
O kọ ọ sibẹ pe: “O buru gan-an o, o riiyan lara gidi ni. Oṣere onitiata Yoruba, Baba Ijẹṣa, to lọọ b’ọmọ ọlọmọ ṣeṣekuṣe lọmọ ọdun meje, to tun pada waa ba a ṣeranu lọmọ ọdun mẹrinla, ha! Ta lo mọ iye eeyan ti oniranu ọkunrin yii aa ti ba laye jẹ ka sọ pe ọwọ o tẹ ẹ. Emi ni mo n ṣagbatẹru ofin ta ko ṣiṣe ẹnikẹni baṣubaṣu. O kere tan, ọdun mẹrinla lẹni to ba jẹbi ẹsun bẹẹ maa lo lẹwọn.
“Gbogbo bo ṣe n rawọ ẹbẹ ninu fọran fidio kan ni mo wo, ṣugbọn ẹbẹ yẹn o ṣetẹwọgba. Ẹ jẹ ki gbogbo wa ṣe ohun ta a ba le ṣe lati ṣatilẹyin fun Princess to gba ọmọbinrin naa ṣọdọ, ki wọn ri i pe ẹjọ yii dele-ẹjọ, ki wọn gbọ ẹjọ naa bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ, ki wọn si wọn ẹwọn fọpa-wọn fun un ni.
Amọ ṣa o, CP Hakeem Odumosu, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko ti sọ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, nipa ẹsun ti wọn fi kan afurasi ọdaran yii pe ko sohun to jọ ifipabanilopọ ninu gbogbo iwadii tawọn ṣe ati ẹri to wa niwaju awọn agbofinro.
Odumosu ni awọn o le tori awijare ki itọ tan lẹnu, awọn o si ni i kọja ohun ti ofin la kalẹ. O ni loootọ ni Baba Ijẹṣa ṣi wa lahaamọ awọn, awọn o ti i gba beeli rẹ, ṣugbọn ẹsun tawọn ka si i lẹsẹ ko kọja pe o fọwọ kan ọmọbinrin naa lọna aitọ, ẹsun naa ko si lagbara ju ohun tawọn le gba beeli rẹ lọ.
O lawọn ti kọwe ẹsun naa si ajọ to n ba araalu ṣẹjọ, to si n gba adajọ nimọran (DPP), o ni imọran ti wọn ba mu wa lori ọrọ yii lawọn maa tẹle, ki i ṣe ariwo tawọn eeyan kan n pa lọtun-un losi.