Faith Adebọla, Eko
Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n daro iku gigbona tawọn afurasi adigunjale mẹta kan, Ọladimeji, ẹni ogun ọdun, Sodiq Taiwo, ẹni ọdun mẹtalelogun ati Rilwan Nasiru, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, fi pa awakọ ileeṣẹ UBER, Stephen Oluwaniyi. Niṣe ni wọn yin ọkunrin naa lọrun pa, wọn si tun gbe mọto ẹ lọ, kọwọ too ba wọn.
Ba a ṣe gbọ, ọjọ kẹfa, oṣu kẹsan-an, ta a wa yii niṣẹlẹ ibanujẹ naa waye, lagbegbe Mẹiran, lọna marosẹ Sango si Eko.
Ninu alaye ti afẹsọna oloogbe naa ṣe nigba to lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa, o ni akẹkọọ-gboye ni ololufẹ oun, ẹkọ nipa iṣẹ dokita lo ka ni fasiti, ṣugbọn airiṣẹ lo mu ko ṣi maa fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ UBER, ti wọn n ṣeto irinajo fawọn eeyan l’Ekoo. Nọmba ọkọ naa ni LAGOS KSF 830 GX.
O ni ẹnikan lo pe e lori aago pe oun fẹẹ haaya ọkọ, ko waa gbe oun, lọkunrin naa ba lọ gẹgẹ bo ṣe maa n lọ tẹlẹ, laimọ pe ajo alọọde lo n lọ. Nigba to ki Stephen pada sile, ti wọn ko ri i ni wọn bẹrẹ si i wa a kaakiri, ki wọn too kan oku ẹ nisalẹ biriiji marosẹ to wa l’Abule Ẹgba.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko ni iwadii awọn fihan pe niṣe ni wọn kọkọ yin ọkunrin naa lọrun, ti wọn si ju oku ẹ latoke sisalẹ biriiji naa.
Bawọn ọlọpaa ṣe gbọrọ yii lawọn ọtẹlẹmuyẹ ti fọn sigboro, ọjọ kẹta, iyẹn ọjọ Wẹsidee, lọwọ ba awọn amookunsika ẹda mẹtẹẹta nibi ti wọn sa pamọ si, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe wọn. Lẹyin naa ni wọn jẹwọ ibi ti wọn gbe mọto ẹni ẹlẹni si, wọn si jẹwọ pe loootọ awọn lawọn pa oloogbe naa, wọn ni mọto ẹ lawọn fẹẹ ji, ṣugbọn o ba awọn ṣagidi ni.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti ni ki iwadii bẹrẹ lori awọn afurasi ọdaran naa, iwadii naa si ti bẹrẹ ni Panti, Yaba, lẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, ti wọn taari wọn si.