Ọlawale Ajao, Ibadan
Agbọ-sọgba-nu gbaa niroyin ọhun jẹ nigba ti awọn afẹmiṣofo kan pa agbẹ kan, Musa Monsuro, sinu oko ẹ lọjọ ọdun Itunu Aawẹ to kọja yii.
Ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ ọdun Itunu Aawẹ la gbọ pe awọn ọdaju eeyan ọhun lọọ ka agbẹ naa mọnu oko kaṣu ẹ to wa labule Ararọmi, niluu Igboọra, ti wọn si ṣa a ladaa yannayanna titi to fi ku.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, fidi iṣẹlẹ to ba ni lọkan jẹ ọhun mulẹ.
O ni lọgan ti wọn ti fiṣẹlẹ ọhun to oun leti loun ti paṣẹ fawọn ọlọpaa atọpinpin lati ṣewadii ọrọ naa, ki wọn si wa awọn ọdaju apaayan ọhun jade kia.
Nigba to n fidi igbesẹ yii mulẹ lorukọ Onadeko, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, sọ pe “iwadii ti n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yẹn. Gbogbo aye ni yoo foju ri awọn ọdaran naa nigba ti iwadii ọhun ba pari”.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana, lawọn ara abule ọhun too fi iṣẹlẹ yii to awọn agbofinro leti. Awọn ọlọpaa naa la gbọ pe wọn palẹ oku agbẹ naa mọ, ti wọn lọọ ṣe e lọjọ si yara igbokuu-pamọ-si nileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ fun ayẹwo.
Ta o ba gbagbe, nitori pipa ti awọn darandaran maa n pa awọn agbẹ nipakupa lagbegbe Ibarapa yii lo mu ki ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ (Igboho Ooṣa), lọọ sọ fawọn to jẹ apaayan laarin awọn Fulani agbegbe naa lati fi ilẹ Yoruba silẹ patapata.