Iwọ naa le kopa ninu eto ‘Arlington Appreciation Day’ ti yoo waye ni orileede Amẹrika

Ọrẹoluwa Adedeji

Anfaani nla ti wa fun awọn ọmọ orileede yii lati darapọ mo ileeṣẹ kan ti wọn pe ni Global Tours and Party Ride LLC, eyi ti wọn ni ẹka ni orileede Amẹrika ati Naijiria, labẹ idari Ambasadọ Oluwafẹmi Ọlayinka Kajọgbọla.

Ileeṣẹ yii lo ṣeto ipade kan ti wọn pe ni Arlington Nigeria Appreciation Day, eyi ti yoo waye ni orileede Amẹrika ni ọjọ kẹwaa si ikẹtala, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, ni Arlinton, ni orileede Amẹrika.

Nigba to n ṣalaye lẹkun-rẹrẹ nipa ipade naa, Ambasadọ Kajọgbọla sọ pe awọn ti ipade naa wa fun ni awọn oloṣelu, awọn ọba, awọn adari ileeṣẹ nla nla, eeyan jankan jankan niluu, ati awọn ti ko ti i de orileede Amẹrika ri, ṣugbọn ti wọn fẹẹ lo anfaani eto naa lati lọ sọhun-un.

 Iranṣẹ Ọlọrun naa ni lọdun to kọja ni awọn ṣe akọkọ iru eto yii, ti ikeji yoo si waye ninu oṣu Kẹsan-an yii. Eto naa lo ni awọn eeyan kaakiri origun mẹrẹẹrin agbaye bii awọn gomina, awọn oloṣelu, awọn ọba alaye, awọn onileeṣẹ nla nla atawọn ti wọn ko ba de Amẹrika ri, ṣugbọn ti wọn fẹẹ lo anfaani eto naa lati wa wa fun. Ọjọ kẹwaa si ikẹtala, oṣu Kẹsan-an lo ni eto yii yoo waye.

Nigba ti ALAROYE ṣalaye fun ọkunrin naa pe oriṣiiriṣii awọn eto bii iru eleyii ni wọn ti fi lu awọn eeyan ni jibiti, Kajọgbọla ni eleyii ko le ri bẹẹ, nitori Ọọni Ileefẹ, Ọba Ogunwusi Ẹnitan, yoo wa nikalẹ nibi eto naa, bẹẹ ni oṣere tiata nni, Ọlaniyi Afọnja, ti gbogbo eeyan mọ si Sanyẹri wa ninu awọn to n bọ, to si tun jẹ ọkan ninu awọn aṣoju fun eto pataki ọhun.

Ninu alaye to ṣe lori bi eeyan ṣe le kopa ninu eto naa lo ti sọ pe ohun akọkọ ni ki tọhun ni iwe irinna, ko si forukọ silẹ fun eto naa. Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (100, 000), eyi ti wọn ni wọn ko ni i da pada (non refundable) ni awọn ti wọn ba nifẹẹ si eto yii yoo fi forukọ silẹ lati kopa nibẹ.  Lẹyin ti wọn ba sanwo yii tan ni wọn maa fi risiiti wọn ranṣẹ si iimeeli (emai address) ileeṣẹ naa. Bi wọn ba ti n fi eleyii ranṣe ni wọn yoo maa gba koodu ti wọn yoo fi fiili fọọmu sori website ileeṣẹ yii.

Lẹyin ti wọn ba ti ṣe eleyii tan ni wọn maa san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira lara owo eto naa, eyi ti wọn yoo fi ṣeto fisa fun wọn. Ti fisa ba ti jade ti onitọhun ri i gba ni wọn yoo ṣẹṣẹ san owo yooku to jẹ mọ irinajo naa. Oriṣiiriṣii ipo ni o wa fun irinajo yii, eyi ti onikaluku ba fẹẹ sanwo fun lo maa ṣe. Awọn to ba fẹẹ ba ijokoo ọlọlaa ti wọn n pe ni (First class) lọ, awọn ti wọn ba fẹẹ ba ẹlẹgbẹ kẹjẹbu lọ ati bẹẹ bẹẹ lọ. O ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta yii wa fun owo lati fi ṣeto fisa ti ẹni ti ko ba ti i ni fisa, to si fẹẹ kopa ninu eto yii yoo san.

O fi kun un pe eto yii ki i ṣe lati ja pa, ẹ ni lati pada ti wọn ba fun yin ni iwe irinna, bo tilẹ jẹ pe ẹ le ṣabẹwo si awọn eeyan yin to ba wa nibẹ. Ṣugbọn ẹ gbọdọ pada si Naijiria.

O ni anfaani wa fun awọn to fẹẹ da iṣẹ silẹ ati beeyan ṣe le lo anfaani to wa nibẹ lati waa da okoowo silẹ ni Naijiria. Kajọgbọla ni eto naa ki i ṣe ayuederu, ijọba mọ nipa rẹ, awọn si ti ṣe iru eto yii lọdun to kọja, ti awọn eeyan si kopa nibẹ daadaa. O ni, Ẹ le lọọ wo awọn eto wa lori awọn ẹrọ alatagba wa fun alaye si i.

Nigba to n fidi eto yii mulẹ, Ọọni Ifẹ, Ọba Ogunwusi rọ awọn eeyan lati kopa ninu eto naa, eyi ti wọn pe ni Arlington Nigeria Appreciation Day. O rọ awọn eeyan lati fọwọsọwọpọ lati mu ki aye ko daa fun gbogbo wa. Bakan naa lo gboṣuba fun awọn to ṣagbatẹru eto naa.

Fun alaye kikun, ẹ le pe sori awọn ẹrọ ibanisọrọ wọnyi: +2348137757079

+2347031631432
+2348168998190
+2348032470050

Leave a Reply