Micheal ji ẹrọ amuletutu mẹsan-an ninu ile ti wọn ni ko maa ṣọ l’Oṣogbo

 Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹni a gboju okun le ti ko jọ ẹni agba ni ọrọ ọmọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Micheal Eze, ẹrọ amuletutu (air conditioners) mẹsan-an lo ji tu ninu ile kan to n ṣọ.

A gbọ pe onile kan ninu GRA, niluu Oṣogbo, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ọṣun, lo gba Micheal gẹgẹ bii ọlọdẹ lati maa ṣọ ile naa.

Ṣugbọn akara ọmọ bibi ipinlẹ Ebonyi yii tu sepo laago meje aabọ aarọ ọjọ Aje, Mọnde, to kọja, iyẹn ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lẹyin to ta ẹrọ amuletutu to ji ninu ile naa fun Hausa kan to n ra ajaku nnkan eelo ile.

Gẹgẹ bi Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Ajagun-fẹyinti Bashir Adewinmbi, ṣe ṣalaye, o ni ọkọọkan awọn ẹrọ ọhun to ẹgbẹrun lọna irinwo Naira, ṣugbọn ẹgbẹrun marun-marun Naira lo ta ikọọkan wọn fun Hausa naa.

O ni lẹyin ti Micheal ta wọn tan ni olobo ta awọn Amọtẹkun, ko si pẹ rara ti ọwọ fi tẹ ẹ, lasiko iwadii iṣẹlẹ naa ni wọn ri meji gba pada ninu awọn ẹrọ amuletutu mẹsan-an to ta gba padalọwọ Hausa to ta a fun.

Adewinmbi sọ siwaju pe Micheal jẹwọ lọfiisi awọn pe ki i ṣe igba akọkọ niyẹn ti oun yoo ji nnkan tu ninu ile ti oun n ṣọ naa, oun si ti ni awọn kọsitọma Hausa ti oun maa n ta wọn fun lowo pọọku.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti fa ọkunrin naa le awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ lọwọ fun itẹsiwaju iwadii, ati ki wọn le foju rẹ ba ile-ẹjọ lati le jẹ ẹkọ fun awọn to ba tun n gbero iru iwa bẹẹ.

Leave a Reply