Adewale Adeoye
Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ, kayeefi lọrọ ọkunrin ọlọpaa kan, Oloogbe Thembelani Lihlume, to yinbọn pa iyawo ile rẹ, Oloogbe Abona Magaba, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ọmọ ọdun kan to n tọ lọwọ, Lihlume Magabe, toun naa si yinbọn para rẹ mọ’nu mọto kan to gbe wa,ṣi n jẹ fun ọpọ eeyan bayii.
Iṣẹlẹ ọhun waye lagbegbe Samora Machel, niluu Cape Town, lorileede South Africa, nibi tawọn obi iyawo ọlọpaa naa n gbe lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
ALAROYE gbọ pe o ti to ọsẹ meji sẹyin bayii ti ija ojoojumọ ti n waye laarin Thembelani ati iyawo rẹ, nigba ti ija naa ko tete pari lo mu ki Oloogbe Abona ti i ṣe iyawo Thembelani, pada sile awọn obi rẹ pẹlu ọmọ ọdun kan to n tọ lọwọ. Ṣugbọn igba gbogbo ni Thembelani maa n wa a lọ sile awọn obi rẹ, ti yoo si bẹ ẹ pe ko tete pada wa sile kawọn tun jọọ maa gbe papọ gẹgẹ bii tọkọ-taya. Gbogbo ẹbẹ ti ọkunrin agbofinro yii n bẹ iyawo rẹ, ẹyin eti obinrin naa lo n bọ si. Ọsẹ yii ni Thembelani fibinu lọọ ba a nile awọn obi rẹ, ṣe lo yinbọn fun iyawo rẹ, Oloogbe Abona, ati ọmọ ọwọ rẹ, Lihlume Magabe, ati aburo iyawo rẹ to wa nibẹ. Lẹyin naa lo ṣẹṣẹ waa yinbọn pa ara rẹ mọ’nu mọto to gbe lọ sọdọ awọn ana rẹ.
Iya iyawo, Abilekọ Nozuko Magaba, sọ pe, ‘Emi gan-an ni Thembelani kọkọ pade lẹnu geeti ile wa, ṣe lo n mu siga, mo sọ ọ fun un pe ko ma mu nnkan to n mu wọnu ile wa, ṣugbọn bi mo ṣe ri i ti oju rẹ ko dara, mo mọ pe o fẹẹ waa ṣiṣẹ laabi kan ni, bẹẹ ni mo pariwo pe ki aburo iyawo ẹ tete tilẹkun pa, ṣugbọn ṣe lo yinbọn soju kọkọrọ, to si jalẹkun wọle. O yinbọn pa iyawo rẹ, ọmọ ọdun kan to n tọ lọwọ ati aburo iyawo rẹ lẹsẹ. Iyẹn ko ku, o n gba itọju lọwọ nileewosan ijọba agbegbe naa bayii.
Ṣaaju akoko yii lo jẹ pe ṣe ni Thembelani fẹsun kan iyawo rẹ pe o n yan ale nita, ṣugbọn ti ọrọ ko ri bẹẹ rara, o tiẹ ti figba kan ba ẹrọ kọmputa rẹ ti wọn gbe fun un nibi iṣẹ jẹ ri, iyawo rẹ lo mọna to gba lati ra omiiran pada nitori dukia ibi iṣẹ rẹ ni. Emi paapaa ko fara mọ ọn pe ko fẹ ọmọkunrin naa, ṣugbọn ọmọ ti wa laarin awọn mejeeji ni mi o ṣe mọ nnkan ti mo le ṣe sọrọ naa mọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Malcolm Pojie, to fidi iṣẹle ọhun mulẹ sọ pe loootọ ni iṣẹlẹ ọhun waye, tawọn si n ṣewadii nipa rẹ. O ni laipẹ yii lawọn maa jabọ iwadii awọn fawọn araalu.